'Mi ò mọ̀ bóyá ọmọ mi ṣì wà láyé lẹ́yìn ọdún méjì tó ti wà ní àhámọ́'

    • Author, Alice Cuddy
    • Reporting from, Tel Aviv
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìyá ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí ikọ̀ ọmọ ogun Hamas fi sí àhámọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ikọlù sí Israel ní ọjọ́ Keke, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 sọ pé òun kò mọ̀ bóyá ọmọ òun ṣì wà láyé.

Àmọ́ ó ní òun ní ìrètí pé ìpè fún àlááfíà èyí tí Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ń gbé máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn tọ wà ní àhámọ́ gba ìtúsílẹ̀.

Herut Nimrodi sọ fún BBC News pé òun ń bẹ̀rù pé kí nǹkankan má ti ṣe ọmọ òun ṣùgbọ́n tó ní ìrètí pé ọmọ òun ṣì wà láyé lẹ́yìn ọdún méjì tó ti wà ní àhámọ́.

Ó ní ọmọ òun ni èèyàn kan ṣoṣo tó kù nínú àwọn tí Hamas kó sí àhámọ́ tí wọn kò ì tíì sọ fún ẹbí rẹ̀ pé bóyá ó ti kú tàbí ó yè.

Ìpè fún àlááfíà èyí tí Trump ń gbé ti ń rí ẹsẹ̀ walẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjíròrò tí ìrètí sì wà pé yóò tẹ́síwájú lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun láàárín Hamas àti Israel lójúnà àti fi òpin sí ogun àti láti tú àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀.

"Wọ́n ti ń gbìyànjú láti fẹnukò láti ọjọ́ pípẹ́ àmọ́ tí kò kẹ́sẹ járí. Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀," Nimrodi sọ. "Ìrètí wà pé èyí ló máa jẹ́ òpin ìfẹnukò wọn."

Ó sọ pé ó ṣe pàtàkì pé àwọn tó wà ní àhámọ́ - yálà wọ́n wà láyé tàbí wọ́n ti kú - ni wọ́n kọ́kọ́ tú sílẹ̀ ní ipele àkọ́kọ́ ohun tí ìfẹnukò wọn bá dá lé lórí.

"Ó pọn dandan láti tú àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ – àwọn tó wà láyé àtàwọn tọ ti jáde láyé. A ò mọ ipò tí òkú wọn wà. Wọ́n nílò láti tú wọn sílẹ̀ kí àwọn ẹbí le mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Kódà, àwọn ẹbí tí wọ́n ránṣẹ́ sí gan pé àwọn èèyàn ti kú ni wọn kò gbàgbọ́ nítorí wọ́n nílò ẹ̀rí láti gbàgbọ́ pé èèyàn àwọn ti jáde láyé lóòótọ́."

Tamir wà lára àwọn èèyàn mẹ́tàdínláàádọ́ta tí Hamas fi sí àhámọ́ lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá tó ṣì wà ní Gaza – ogún nínú wọn ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ṣì wà láyé.

Ìgbà tó rí ọmọ rẹ̀ kẹ́yìn ni nínú fídíò lórí ayélujára tí wọ́n ti ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn Hamas ti jigbé.

"Ọmọ mi obìnrin tó kéré jùlọ ló sáré pariwo wá bámi pé òun rí ẹ̀gbọ́n òun nínú fídíò kan lórí Instagram pé wọ́n ti jigbé."

"Mo rí Tamir nínú aṣọ oorun rẹ̀, kò wọ bàtà, kò wọ ìgò ojú rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ lè má ríran láì wọ ìgò ojú."

Láti ìgbà tó ti rí ọmọ náà kẹ́yìn - ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní iléeṣẹ́ ológun nígbà náà tí ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ méjìdínlógún, tí wọ́n wà ló sí Gaza – kò ì tíì gbọ́ bóyá ó wà láyé láti ìgbà náà.

"Òun nìkan ni ọmọ Israel tí a kò gbọ́ bóyá ó ṣì wà láyé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́."

Bákan náà ni wọn kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bipin Joshi tí òun náà jẹ́ ọmọ Nepal.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹbí míì tí wọ́n pa èèyàn wọn tàbí jígbé lọ́jọ́ náà tí BBC bá sọ̀rọ̀, Nimrodi ní níṣe ló dàbí pé ilé ayé dúró sójú kan fún ọdún méjì báyìí.

Ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún jẹ́ ọjọ́ tó burú jùlọ fún Israel bí ikọ̀ Hamas ṣe pa èèyàn 1,200 tó jẹ́ ọmọ Israel, tí wọ́n sì fi 251 sí àhámọ́ ní àwọn ìlú tó wà ní ẹkùn gúúsù Israel.

Ìkọlù náà ṣokùnfà ogun èyí tó ti mú ẹ̀mí èèyàn tó lé ní 67,000 ní Gaza látọwọ́ àwọn ológun Israel gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń darí rẹ̀ ṣe sọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tis á kúrò ní agbègbè náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ohun amáyédẹrùn sì ti di bíbàjẹ́.

Nimrodi sọ pé ilé ní òun wà lẹ́bàá Tel Aviv nígbà tí òun gba àtẹ̀jíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Tamir ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà láti ibi tó wà ní ẹnubodè àríwá Gaza pé níṣe ni àdó olóró ń dún lákọlákọ.

Tamir sọ fun pé òun máa padà sílé láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ nígbà tí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá wáyé nítorí ipò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun.

Kò ju ogún ìṣẹ́gún lọ sígbà tí ọmọ rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀ ló gbọ́ pé wọ́n ti jí ọmọ rẹ̀ gbé.

Láti ìgbà náà ló ti ń gbìyànjú láti rip é ọmọ rẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ tó fi mọ́ ṣíṣe ìwọ́de pẹ̀lú àwọn òbí míì tí ọmọ wọn wà ní àhámọ́.

Ó fi kun pé àwọn ọjọ́ míì wà tí òun kò ní lè jáde, tí òun sì máa tẹ̀lé ọkàn òun nítorí ọjọ́ mélòó ló kù mọ́ fún òun.

Láti ìgbà tí èròńgbà láti pẹ̀tù sí àáwọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ tó sì ti ń di ohun tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ìrètí ti wà fún àwọn ẹbí tó ṣeéṣe kí àwọn èèyàn padà sílé láìpẹ́.

Nimrodi darapọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn – tó fi mọ́ ẹbí àwọn èèyàn tó ṣì wà ní àhámọ́ àti àwọn èèyàn tó ti fìgbà kan rí wà ní àhámọ́ fúnra wọn – tó pé sí Tel Aviv lálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta láti pè fún ṣíṣe ìjíròrò lórí bí ogun ṣe máa dáwọ́ dúró.

Ó wọ aṣọ tí wọ́n ya àwòán ọmọ rẹ̀ síwájú rẹ̀, tó sì ń rẹ́rìn-ín.

"Mo ní ìgbàgbọ́ ní ìpè fún àlááfíà yìí, mo gbàgbọ́ pé Trump kò ní jẹ́ kí èyí bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́."

Bákan náà ló ké sí olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu láti ṣe gbogbo nǹkan tó tọ́ "dá àwọn tó wà ní àhámọ́ padà sílé, kí o sì rip é àlááfíà jọba ní ẹkùn yìi."

Ó ní nígbà tí òun bá fẹ́ sùn n òun máa ń rántí ojú ọmọ òun bí ó ṣe rí nígbà tí wọ́n ji gbé.

"Láti máa ní ìrètí fún ọdún méjì jẹ́ ohun tó ń àárẹ̀ ọkàn."