You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tírélà tẹ bàbá tó gbé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílé ẹ̀kọ́ pa l'Ondo
Iṣẹju kan pere lo wa laaarin iku ati iye ti Yoruba n wi ki i ṣe awawi rara. Bẹẹ lo ri fun baale ile kan to padanu ẹmi rẹ laaarọ Ọjọru ana, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2025, nipinlẹ Ondo.
Ọkunrin ti ko ti i sẹni to mọ orukọ rẹ naa ja awọn ọmọ rẹ to gbe lọ sileewe silẹ tan lo pade iku ojiji loju ọna Oda, ni ilu Akure.
Alaye awọn o ṣoju mi koro ni pe ọkada ni baale ile naa fi gbe awọn ọmọ rẹ lọ sileewe, o si ti fa wọn le awọn olukọ lọwọ tan.
Bo ṣe yiju ọkada pada to kọri si ọna ile ni tirela kan ti wọn ni ere buruku lo n sa bọ, run un pa.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ yii ṣoju rẹ, ṣalaye pe laaarin ka diju ka la a ni iṣẹlẹ aburu yii fi waye.
O ni bo tilẹ jẹ pe ere buruku ni tirela naa n sa bọ, ko sẹni to mọ bo ṣe sare rọlu ọlọkada to n pada lọ sile naa to si pa a.
Ohun ti a gbọ ni pe dẹrẹba to wa tirela ọhun padanu ijanu ọkọ naa ni.
Ẹsẹkẹsẹ to run baale ile naa mọlẹ lo dagbere faye, dẹrẹba to wa tirela naa si fẹsẹ fẹ ẹ.
Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, wọn ko ti i gbuuro rẹ tabi ri i mu rara.