Ìjọba Saudi Arabia kéde ìjìyà tuntun fún àwọn tó ń wọ ilẹ̀ náà lọ́nà àìtọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹka to n ri si ọrọ abẹnu lorilẹede Saudi Arabia ti bẹrẹ igbesẹ tuntun bayii lori awọn to ba wọ ilu naa lati ṣe Haji lọna aitọ.

Gẹgẹ bi ẹka naa ṣe ṣalaye, owo itanran ti i ṣe ẹgbẹrun lọna ogun Riyal, ( 20,000 riyal) owo ilu naa ni ẹni to ba lufin yii yoo san.

Lara awọn ọran ti eeyan le da ti yoo fi lufin ọhun ni kiko awọn eeyan wọ Saudi lọna to lodi sofin.

Pipese ilegbee fun awọn ti ko ni iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ Haji, gbigba fisa fun wọn tabi pipese ilana miran ti yoo gbe wọn wọlu.

Nipa igba ti ofin yii yoo gbera sọ, ọjọ akọkọ ninu oṣu Dhul-Qi'idah, eyi ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii, titi di ọjọ kẹrinla, oṣu Dhul-Hijjah, iyẹn ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni.

Wọn fi kun un pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ nibi to ti n gbiyanju lati gba ọna ẹyin ṣiṣẹ Haji yoo ba ara rẹ niluu rẹ kia.

Iyẹn ni pe wọn yoo le e jade kuro ni Saudi Arabia lọ si orilẹede rẹ, wọn yoo si tun fofin de e lati ma wọ Saudi fun ọdun mẹwaa gbako.

Iru owo yii kan naa ni wọn ni ẹni to ba n lo fisa to ti lejọ yoo san pẹlu.

Saudi sọ pe ẹni ti fisa rẹ ba ti lejọ to si tun n fẹsẹ palẹ ni Mecca tabi Medina yoo ni lati sanwo yii pẹlu.