You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Èmi nìkan ni mo móríbọ́ nínú bàlúù tó já lulẹ̀, odidi ọjọ́ mẹ́jọ ni mo dánìkan lò nínú igbó'
- Author, Asya Fouks
- Role, BBC Lives Less Ordinary
- Author, Edgar Maddicott
- Role, BBC Lives Less Ordinary
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Annette Herfkens n ṣe faaji isinmi lẹyin iṣẹ lorilẹede Vietnam pẹlu afẹsọna rẹ ki baalu kan ti wọn wa ninu rẹ to ja ti gbogbo awọn to wa ninu baluu naa si jade laye ayafi oun nikan.
Ọdun 1992 ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Annette Herfkens ati afẹsọna rẹ, Willem van der Pas tabi 'Pasje' gẹgẹ bo ṣe maa n pe e n lọ si eti omi okun kan ni Vietnam.
Annette n ṣiṣe ni ẹka isiro ni Madrid lọdun naa lọhun ko to bẹrẹ ere ifẹ pẹlu Pasje'ti wọn jọ kawe ni fasiti lati ọdun 1979.
Aarin irinajo naa lati ilu Ho Chi Minh lọ si agbegbe Nha Trang ni wón wa ki baalu wọn to koju iṣoro kan latari oju ọjọ ti ko ṣe dede to si ja lulẹ si agbegbe kan ninu aginju ti ọpọ oke nlanla wa.
Ialulẹ naa le to bẹẹ ti awọn arinrinajo ọgbọn to ku ninu baalu ọhun padanu ẹmi wọn, to fi mọ afẹsọna rẹ, Pasje'.
Odidi ọjọ mẹjọ ni obinrin naa fi wa ninu aginju pẹlu ipalara, to si n farada irora nla pẹlu oniruru egungun ara rẹ to ti kan. Bẹẹ ni ko ri omi mu yatọ si pe o n ṣọfọ ololufẹ rẹ to ku.
Bi ere ifẹ wọn ṣe bẹrẹ
Ere ifẹ awọn mejeji bẹrẹ pẹlu pipe ara wọn nija.
Annette ṣalaye pe "O ni, ṣe ohun kan ti o ko ni fẹ ṣe laye ara rẹ." Ipenija naa ni pe ki n fẹnu ko Pasje lẹnu.
Ọr ni awọn mejeji ṣaaju askoko yii ti wọn si n gbe ni ilegbe awọn akẹkọọ kan naa.
Odidi ọdun mẹtala gbako ni wọn fi fẹ ara wọn ki Pasje to ni ki wọn ṣe faaji lọ si Vietnam. Fun oṣu mẹfa lawọn mejeji fi n ṣisẹ ni orilẹede ọtọtọ lorilẹede; Vietnam ati Spain.
Lẹyinorẹyin wọn pade, wọn si n lọ si Vietnam fun isinmi wọn amọ nigba to ku iṣẹju marun un ki baalu wọn balẹ ni o bẹrẹ si n yiwọ.
Ẹrọ baalu ọhun mejeji kọṣẹ, o bẹrẹ si n jabọ lati oke ko to lọ fori sọ inu aginju kan .
Ẹni kan ṣoṣo ti ori ko yọ
Lẹyin ijamba naa, ariwo kokoro inu igbo atawọn ọbọ lo ji Annette.
O ni "Mo yi aga kan kuro lori mi, oku ọkunrin kan lo wa nibẹ.
"Bi mo ṣe yi kuro lori mi ni ọkunrin naa jabọ lori aga ọhun."
Apa alaafia rẹ ni Pasje wa lori aga tirẹ naa amọ o ti jẹ ipe Eledua.
Annette ni "Ohun ti mo ri ni pe mo wa ninu igbo, pẹlu ọpọlọpọ igi layika mi, bẹẹ ni mo n jẹ ọpọ irora.
Ẹṣe rẹ ti kan, bẹẹ naa ni egungun ibadi rẹ kan ni ibi mejila, to fi mọ egungun agbọn rẹ pẹlu.
Baalu naa kọlu apata nla kan, iyẹ apa rẹ kan foyọ danu, o tun lọ fori sọ apata nla mii ko to takiti.
O ni oun n gbọ ti awọn eeyan n kigbe oro o, oro o, amọ nigba ti yoo di aṣalẹ, ko gbọ ohun ẹnikẹni mọ.
Ọmọ igboro to di ero inu igbo
Ninu irora rẹ lo ti n ba ọkunrin ọmọ Vietnam kan sọrọ amọ ọkunrin ọhun ku.
Lẹyin iku ọkunrin naa, Annette ko fi ẹgbẹ rẹ silẹ ko ma ba ku oun nikan ninu igbo ti wọn wa.
Nigba to ya, o ni "Mo kuro nibẹ lasiko to bẹrẹ si n jẹra, kaka ki n maa wo o, niṣe ni mo wa n wo ẹwa inu akinju ọhun.
"Bi mo ṣe n wo awọn ewe inu igbo naa ni mo tunbọ n ri bo ṣe lẹwa to."
Annette to jẹ ọmọ igboro to maa n rinrinajo lọ sawọn ilu nla bii New York ati London ti di ẹni ti n fi inu igbo ṣebugbe.
Lasiko kano jo bẹrẹ si n rọ ninu aginju, o ni ewe loun fi n gbe omi ojo mu, ti omi naa si sun lẹnu oun bii ọti champagne olowo iyebiye.
O ni igba naa loun to mọ iyi wiwa laaye ati wiwa laaye ara ẹni.
'Mi o ronu nipa Pasje mọ'
"Mi ni ohun miran ti mo le ṣe mọ ju ki n gbiyanju lati gbagbe nipa iku Pasje.
"Ni gbogbo igba ti mo ba ranti rẹ ni mo maa n wo oruka €10 to ra fun ni Leiden, Netherlands, ti ọwọ mi ti wu ninu rẹ lẹyin ti kokoro ti jẹ mi daadaa.
"Mo gbagbọ pe igbeyawo wa yoo dara ti a ba fẹ ara wa sile. Ọrẹ timọtimọ ni wa, o jẹ eeyan daadaa, o rẹwa amọ kii ṣe bii ẹni to mọ iyi ara rẹ.
Annette gba ara rẹ niyanju lati ma ronu nipa ọkunrin naa ninu igbo to wa. O ni "Mo maa n sọ fun ara mi pe 'ma ronu nipa Pasje.'"
Amọ ni akoko kan, ara rẹ bẹrẹ si n rẹwẹsi latari egbo to wa nibẹ to fi mọ airi ri ounjẹ jẹ.
O ni "Nigba ti yoo di ọjọ kẹfa, mo ti bẹrẹ si n ku sara…."
Amọ lojiji lo ri ọkunrin kan to wọ aṣo alawọ ọsan.
O ke pe ọkunrin naa fun iranlọwọ pẹlu igbagbọ pe iya oun fun ọjọ mẹjọ ninu aginju ti dopin.
Ibẹrẹ igbeaye tuntun
Nigba ti Annette de siluu Ho Chi Minh, o ba iya rẹ atawọn ibatan afẹsọna rẹ naa nibẹ, to fi mọ alabaṣisẹ rẹ kan, Jaime.
O ni "Gbogbo awọn mọlẹbi mi lo ro pe mo ti dagbare faye."
Ṣaaju lawọn eeyan ti n mura eto isinku rẹ, koda wọn ti kede ninu awọn iwe iroyin nipa iku oun ati afẹsọna rẹ ọhun.
O ni "Gbogbo eeyan lo gbagbọ pe mo ti ku amọ alabaṣiṣẹ mi, Jaime nikan lo ni ko ṣeeṣe ki n ti ku, o si maa n ba gbogbo awọn to ba sọrọ mii ni ẹni ana ja."
Ibẹrẹ aye tuntun
Ko rọrun fun Annette lati bẹrẹ igbeaye ọtun lai si ololufẹ rẹ nibẹ.
O ni "Bi mo ṣe n dagba, mo n ri awọn ohun tuntun to yẹ ko gbe ṣe nile aye amọ ti iku ko jẹ ko ṣe."
Lẹyin ijamba naa ni ọpọ awọn akẹgbẹ wọn bẹrẹ si n ṣe igbeyawo eyii to mu ko ṣoro pupọ fun latari iku afẹsọna rẹ.
Lakoko igba kan, o tilẹ sọ pe oun ko ni lọ sile ọkọ mọ.
Ṣugbọn ọrẹ rẹ kan gba a nimọran pe ẹnikan ṣoṣo lo le wọ bata ti Pasje bọ silẹ, ẹni naa si ni Jaime to wọ ọkọ ofurufu lọ bẹẹ wo ni Vietnam lẹyin ijamba ọkọ ofurufu naa.
Lẹyinorẹyin, oun ati Jaime fẹ ara wọn, wọn si bi ọmọ meji funra wọn.