Arábìnrin ẹni ọdún 54 bí ọmọ kẹtàdínlógún

Arábìnrin ẹni ọdún 54 bí ọmọ kẹtàdínlógún

Arabinrin ẹni ọdun mẹrinlelaadọta kan ti bi ọmọ kẹtadinlogun ni ileto kan lorilẹede India.

Amọṣa o kii ṣe owo lo pọ to bẹẹ ti wọn fi bi ọmọ pupọ, nitori iwadii BBC News finhan pe inu oṣi ati iṣẹ ni ẹbi naa n gbe, koda akisa ni wọn si n ṣa jẹun, ti wọn n ṣa idọti ati aloku irin kiri lori akitan lati ta.

Ọjọ ori arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Rekha Bai ati iye awọn ọmọ to bi ṣi n ya awọn dokita lẹnu.

Ninu ọrọ rẹ, Dokita Roshan Darangi ti Ileewosan alabọde Jhadol ṣalaye pe 'Iyalẹnu ni ọrọ rẹ jẹ fun wa.Bawo ni eyi tilẹ ṣe ṣeeṣe?'

"Bawo lo ṣe ṣeeṣe lati bi ọmọ to pọ to bayii? Mi o ri iru eeyan bayi ri o.Mo si ti n lo ọdun meji atabọ nibi yii. Boya mo ti ri obinrin to ni ọmọ marun un tabi mẹfa; Ṣugbọn eyi ṣe ara ọtọ."

Marun un ninu awọn ọmọ Rekha ni wọn ku ni rewerewe nitori kokoro arun. O ni iṣoro ile gbigbe kun ara ohun to n ba ẹbi naa finra.

Rekha funrarẹ ṣalaye pe iya n bao un finra gidigidi nitoripe 'A ko ni ibi ti a n gbe. Nitori ojo n rọ gidigidi."

"Ile ẹgbọ̀n mi ọkunrin ni mo n gbe lati nnkan bi ọjọ mẹta si mẹrin bayii; Ṣaaju, abẹ atibaba nibikibi ti a ba ri lẹgbẹ titi la n sun."

Awọn alamojuto ilera awọn ọmọde sọ pe o yẹ ki wọn tubọ tẹmpẹlẹ mọ ilanilọyẹ fetosọmọ bibi.

Ajọ UN sọ ọ ninu abọ iwadii iye onka eeyan agbaye lọdun 2025 ti ajọUNFPA gbe sita pe biliọnu kan ati ọtalelerinwo ẹgbẹrun, (1.4 bilion) eeyan to wa lorilẹede India lọdun 2025.