Ọkọ̀ mẹ́rin forí sọ ara wọn lójú pópó, èèyàn 46 jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan mẹrindinlaadọta to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọpọlọpọ ọkọ kọlu ara wọn ni Uganda.

Ṣaaju ni ọlọpaa ti kọkọ kede pe eeyan mẹtalelọgọta lo ku amọ wọn pada sọ pe ko ri bẹẹ nitori niṣe lawọn ṣiro awọn to daku mọ awọn to jade laye.

Ijamba naa waye lasiko ti ọkọ meji to n rinrinajo fori sọ ara wọn loju popo lasiko ti wọn n gbiyanu lati sare kọja awọn ọkọ mii loju ọna marosẹ Kampala si Gulu.

Ọkan ninu awọn ọkọ naa ya bara kuro loju ọna lasiko to n gbiyanju ko ma fori sọ ọkọ mii amọ asiko to n ṣe eyii lo lọ fori sọ ọkọ bọọsi mii to n bọ niwaju rẹ.

Bi awọn bọọsi naa ṣe fori sọ ara wọn lawọn ọkọ mii to n bọ lẹyin tun bẹrẹ si n ko sinu ijamba to wa nilẹ tẹlẹ.

Ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori ohun pato to ṣokunfa ijamba ọhun.

Ẹni to gbẹnusọ fun ọlọpaa ni awọn ti ko awọn to farapa ninu ijamba naa lọ si oniruru ile iwosan niluu Kiryandongo fun itọju.

Ninu atẹjade kan, ọlọpaa ni awọn n ṣisẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ eto ilera lati mọ iye eeyan ti ọrọ naa kan ni pato ki wọn le bun araalu gbọ bi iwadii ṣe n tẹsiwaju.

Amọ agbẹnusọ ọlọpaa agbegbe naa, Julius Hakiiza ti di ẹbi iṣẹlẹ ọhun ru "awakọ to n gbiyanju lati sare kọja awọn ọkọ mii loju popo."

O sọ fun BBC pe "o fori sọ ọkọ mii to n bọ ni ọna tirẹ."

Hakiiza sọ pe ọkọ mẹrin ọtọtọ lori fori sọra wọn ninu ijamba ọhun.

Aarẹ Yoweri Museveni sọ pe ibanujẹ ọkan ni oun fi gba iroyin ijamba naa, lẹyin naa lo ba awọn mọlẹbi gbogbo awọn ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun.

Museveni tun kilọ fun awọn awakọ ki wọn maa ro ti ẹlomiran ki wọn si maa ṣọra ṣe loju popo.

Lẹyin naa lo paṣẹ ki ijọba fun gbogbo mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ni miliọnu mrun un owo ilẹ naa to jẹ $1,430 tabi £1,070.

Bẹẹ lo tun sọ pe ijọba oun yoo fun awọn to farapa nibẹ ni miliọnu kan owo orilẹede ọhun.

Oju ọna marosẹ ilu Kampala to jẹ olu ilu orilẹede naa ni iha ila oorun si ọna to lọ si guusu ni ọkan lara awọn opopona ti ọpọ ero maa n lo julọ lorilẹede ọhun.

Ni bayii, ọlọpaa ti kilọ fun awọn awakọ ki wọn maa ṣọra fun sisare asapajude lọna ati kọja ọkọ mii loju popo latari pe igbesẹ naa lo n ṣokunfa ijamba ọkọ nibẹ.