You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀kànlá nínú 303 tilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic ní Niger bọ́ lọ́wọ́ agbebọn, bí Gómìnà Kebbi ṣe fẹ́ fa akẹ́kọ̀ọ́ 24 tó dé láti ọ̀dọ̀ ajínigbé, lé òbí wọn lọ́wọ́
Lonii ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ni ijọba ipinlẹ Kebbi n gbero lati dawọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ Maga Girls school to moribọ lọwọ awọn ajinigbe pada fawọn obi wọn.
Lanaa ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kọkanla ni wọn doola awọn akẹkọọ naa lakata awọn ajinigbe.
Idunnu ṣubu layọ fawọn ẹbi atawọn eeyan ipinlẹ Kebbi to fi mọ ijọba nigba tawọn akẹkọọbinrin naa moribọ lọwọ awọn ajinigbe.
Ti ẹ o ba gbagbe, lẹyin ijinigbe awọn akẹkọọ naa ni Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki minisita eto aabọ, Bello Matawalle, lọ duro si ipinlẹ Kebbi titi tawọn akẹkọọbinrin naa yoo fi gbominira.
Ẹwẹ, Gomina Nasir Idris ipinlẹ Kebbi sọ pe ijọba fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa balẹ lẹyin ti Aarẹ paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto aabo lati ṣawari awọn ọmọ naa.
''Aarẹ paṣẹ fawọn ọmogun wi pe wọn gbọdọ wa awọn akẹkọọbinrin to wa lakata awọn ajinigbe ri.
Nigba tawọn ọmọ naa de ni a sọ fawọn obi wọn pe awọn ọmọ wọn ti de, wọn o si ni ipalara kankan.
A dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu atawọn ọmogun naa fun igbiyanju lati doola awọn akẹkọọbinrin yii.
Ko si iyọnu kankan fawọn ọmọ naa, a si ti ranṣẹ sawọn obi wọn lati wa gba wọn pada,'' Gomina ipinlẹ Kebbi lo sọ bẹẹ.
''Ijọba ko sanwo itusilẹ fawọn ajinigbe lori awọn akẹkọọbinrin tawọn ọmogun doola''
Lori ibeere ti ọpọ eeyan ti n beere bo ya ijọba sanwo gọbọi fun itusilẹ awọn akẹkọọ naa, gomina ni ko si ohun to jọ sisan owo itusilẹ fawọn ajinigbe fun itusilẹ awọn akẹkọọ naa.
''Mo n fi dayin loju wi pe ijọba Kebbi ko san kọbọ lori awọn awọn akẹkọọbinrin wa.
Awọn ọmogun naa si sọ fun wa pe awọn o sanwo itusilẹ fawọn ọmodebinrin naa.''
Lọjọ Aje to lọ yii lawọn janduku agbebọn ya wọ ile ẹkọ girama Maga Girls School ni ijọba ibilẹ Danko-Wasagu nipinlẹ Kebbi nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ gbe lọ.
Iyẹn ko tii tan nilẹ nigba ti iroyin ijinigbe akẹkọọ 265 mii ni ile ẹkọ St Mary's Secondary School ni Kwantagora, ipinlẹ Niger tun tẹle e.
Bakan naa ni iṣẹlẹ iṣekupani ati ijinigbe nipinlẹ Kwara naa ko gbẹyin.
Ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe yii ti di nnkan tawọn eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara ni Naijiria ati nilẹ okeere.
Awọn ẹṣọ eleto aabo ti doola akẹkọọ mọkanla St Mary's lakata ajinigbe
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Niger, Umar Bago, ti sọ fun BBC wi pe awọn ẹṣọ eleto aabo ti doola akẹkọọ ile ẹkọ St Mary's mọkanla lọwọ awọn ajinigbe.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC, Gomina Bago, sọ pe ''awọn ẹṣo eleto aabo pẹlu iranlọwọ araalu ri mọkanla ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe gba pada lati inu oko kan.
Amọ, gomina kọ lati sọ bi eeyan ṣe le dawọn ọmọ to moribọ ọhun mọ.
Gomina ipinlẹ Niger tun sọ pe irọ ni iroyin to ni awọn ọmọ ti wọn ji gbe le ni ọdunrun un.
Gomina Bago ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ko sọ pato iye akẹkọọ ti wọn ji gbe lọ.
Ọgbẹni Bago tun sọ pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa kọ eti ikun si ikilọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo nigba ti wọn ṣi ile ẹkọ naa ṣaaju iṣẹlẹ to waye nibẹ.
Gomina ipinlẹ Niger fikun ọrọ rẹ pe ijọba ti sọ fawọn obi wi pe ki wọn wa forukọ iye ọmọ wọn ti wọn o ri mọ nile ẹkọ naa silẹ, amọ, o ni obi mẹrinla pere lo tii forukọ silẹ.
Bago ni gbogbo ile ẹkọ onileegbe to wa lagbegbe Papiri nipinlẹ Niger ni yoo si wa ni titi pa titi tọrọ awọn ajinigbe yii yoo fi lọọlẹ.