Ọlọ́pàá dóòlà èèyàn méjì lẹ́yìn ìkọlu sì àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní Anambra

Àwọn òṣìṣẹ́ alaabo ti doola eeyan meji ti àwọn agbébọn gbé lọ, lasiko ti wọn kọlu àwọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣojú America, ni ìjọba ibilẹ Ogbaru, nipinlẹ Anambra.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ni Ipinlẹ Anambra, DSP Ikenga Tochukwu, lo fi ikede naa sita.

DSP Tochukwu sọ pe àpapọ̀ awọn òṣìṣẹ́ lati àwọn Iléèṣẹ́ ètò ààbò, lo doola awọn eniyan naa.

Ọjọ Ìṣẹ́gun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣù Karùn-ún, ọdún 2023, ni àwọn agbébọn kọlu awọn oṣiṣẹ náà, ni oju ọna Atani si Osamala.

Kọmíṣánnà ọlọpaa nipinlẹ Anambra, Echeng B. Echeng, sọ pe eeyan méje - ọlọpaa mẹ́rin ati òṣìṣẹ́ America mẹ́ta, ni wọn pa.

Wọn si tun dana sun oku wọn mọ inu ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn.

Ipinlẹ Eko ni àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ aṣojú America ọ̀hún ti rinrin ajo lọ si Anambra, lati ṣe agbeyẹwo ipa ti omiyale ní ijọba ìbílẹ̀ Ogbaru.

Ko si ọmọ ilẹ̀ America kankan to kagbako ninu iṣẹlẹ naa.

Botilẹ jẹ pe ko tii si ẹ̀rí to fi múlẹ̀, Ọgbẹni Echeng sọ pe awọn ọmọ ikọ̀ ESN, ikọ̀ agbébọn ninu ẹgbẹ́ IPOB, lo ṣe ìkọlu naa.

Bákan naa lo sọ pe ọwọ́ tẹ eeyan meji, to n ran àwọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

Iye ìgbà tí ìkọlu ti wáyé ní Ogbaru

Lọjọ kẹrin, oṣù Kẹta, 2023, wọn pa ọlọpaa kan, lasiko ti awọn agbebọn kọlu ibudo kan ti àwọn ọlọpaa ti n da ọkọ duro fun ayẹwo ni agbegbe Atani.

Ọlọpaa mẹrin lo tun kú, lasiko ìkọlu si olú ileeṣẹ ọlọpaa ni Atani, lọjọ kẹtàlá, oṣu kẹrin, ọdún 2023.

Sugbọn ṣá, àwọn ikọlu kan ti waye ri laarin awọn agbébọn ati awọn òṣìṣẹ́ alaabo, lati bi ọdún 2020.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣù Kẹfà, ọdun 2022, ileeṣẹ ológun Naijiria pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Ogbaru.

Ipaniyan naa fa ifẹhonuhan lori ayelujara, fun ọpọlọpọ ọjọ.

Àmọ́ awọn alaṣẹ sọ pe, awọn agbebọn to pàgọ́ sinu aginjù nla kan to fẹ lati Ogbaru si Ihiala, ni awọn pa.

Lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karùn-ún, ọdún 2021, ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi, wọ̀yá ija pẹlu awọn agbebọn, ní ìlú Ochuche. Sugbọn ko si ẹni tó kú.

Ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejì, ọdun 2022, awọn ọmọ ogun ori omi pa eeyan kan, wọn si mu àwọn mẹrin. Wọn ní afurasí ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ni wọn - wọn ri ìbọn meji, ati àdá gba lọwọ wọn.

Iléèṣẹ́ ọmọ ogun ori omi, tun pa afurasí agbébọn mẹ́wàá, ninu aginju Ochan, lọjọ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣu Kejìlá, ọdun 2021. Aginjù naa pààlà pẹlu Ogbaru ati Ihiala.

Ìjọba ìbílẹ̀ Ogbaru, wà lara awọn mẹ́jọ, nibi ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Anambra, ti kéde isede, ni oṣu Karùn-ún, ọdún 2022.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yòókù ni Aguata, Ihiala, Ekwusigo, Nnewi North, Nnewi South, Orumba North ati Orumba South.

Ìjọba sọ pe eto ààbò to dẹnu kọlẹ ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ naa lo fa ikede naa.