Èèmọ̀ wọ̀'lú: Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún pa bàbá rẹ̀ tó jẹ́ Olóyè ìlú ní Kwara, ó kun ún wẹ́lẹ wẹ̀lẹ bíi adíyẹ Kérésì

Gende ’kunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Saidi Musa Elemosho, ni BBC Yoruba gbọ pe, o pa baba rẹ, Muṣa Adeyi, to jẹ Oloye Elemosho iluu Share nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara.

Ọkan lara awọn olugbe iluu Share ṣalaye fun BBC Yoruba pe, afurasi Saidi, lo lọọ fa wahala ni ilu Sharaji, Isalẹ Tapa, ti o paala pọ pẹlu iluu Share.

Awọn ara ilu naa si wa fẹjọ rẹ sun baba rẹ, iyẹn Oloye Musa Ẹlẹmọshọ, ti baba naa si ran awọn eniyan kan lọ si ibi ti Saidi ti lọọ fa wahala lati lọọ bẹbẹ.

Ẹwẹ, ki wọn too de, Saidi ti pọn ada to si kun baba rẹ bii ẹran.

O tẹsiwaju pe bo ṣe yọ oju ṣọtọ, lo yọ eti ṣọtọ, to si tu gbogbo ẹya ara baba rẹ kalẹ lekiri-lekiri.

O fi kun pe bi o se pa baba rẹ tan ni o salọ ori oke kan ninu iluu naa ko to di pe ọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ.

Saidi ni wọn wọ de iwaju ileẹjọ majisireeti lori ẹsun ipaniyan ọhun.

Iwe awọn ọlọpaa fihan pe, afurasi Saidi kun Baba rẹ bii ẹran lori ẹsun pe oloogbe naa sepe fun oun lai nidi pataki kan.

Ọlopaa to gbe ẹjọ ọhun wa sileẹjọ, Abdullah Sanni, sọ fun Majisirireeti Muhammed Dasuki pe ẹjọ naa kii ṣe eyi ti wọn fi lee gba oniduro ofunrasi naa.

Majisireeti Dasuki waa paṣẹ ki wọn fi Saidi pamọ si ọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu kini, ọdun 2024.