Nkò wẹ̀, nkò jẹun fún ọjọ́ mẹ́rin láhàámọ́ ọlọ́pàá - Peller, gbajúmọ̀ orí ayélujára

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Odọmọkunrin to jẹ gbajugbaja lori ikanni ayelujara nni, Habeeb Hamzat tọpọ awọn eeyan mọ si Peller ti sọ nipa iriri rẹ lahaamọ ọlọpaa.
Peller sọ pe ọpọ nnkan loju oun ri ni gbogbo ọjọ mẹrin toun lo lahaamọ ọlọpaa, lara eyi to loun ko wẹ, oun ko tun jẹun.
Ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja ni ọlọpaa gbe Peller, ẹni ọdun mọkanlelogun lagbegbe Lekki, nipinlẹ Eko, lẹyin to ni faakaja pẹlu awọn ọlọpaa lori ọkọ ayọkẹlẹ to gbe jade lai ni nọmba idanimọ.
Ori ikanni ayelujara ti wọn pe ni 'Snapchat' ni Peller ti tu aṣiri yii, lasiko to n jẹ ki awọn ololufẹ rẹ mọ adojukọ to koju lahaamọ.
Ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja ni ọlọpaa gbe Peller, ẹni ọdun mọkanlelogun lagbegbe Lekki, nipinlẹ Eko, lẹyin to ni faakaja pẹlu awọn ọlọpaa lori ọkọ ayọkẹlẹ to gbe jade lai ni nọmba idanimọ.
Kete ti Peller gba itusilẹ lahaamọ ọlọpaa naa, lo ti sare gba ori ayelujara lati ṣalaye nipa ohun ipenija rẹ, to si loun ko le gbagbe.
Ọdọmọkunrin naa ṣalaye pe igba akọkọ ree nile aye oun, toun yoo koju iru ipenija bayii.
"Mo ti burẹwa bayii, nko le gbe oju mi sita lasiko yii. Ọmọ, mo sun ni ahaamọ fun ọjọ mẹrin gbako. Eleyii ko tii ṣẹlẹ si mi ri latigba ti mo ti de ile aye," Peller kọ ọ bẹẹ.
Siwaju sii lo tun sọ pe gbogbo awọn toun ba ninu ahaamọ naa ni wọn da oun mọ, koda to tun sọ pe wọn pe oun ni olori awọn lasiko toun fi wa nibẹ.
"Nko jẹun fun ọjọ mẹrin to dara, nko tun wẹ," o sọ bẹẹ.
O wa jẹ ko di mimọ pe oun tun ti kọ ẹkọ to dara, ti yoo jẹ koun maa gbe igbe aye niwọn-tunwọnsi, pẹlu afikun wi pe oun yoo yago fun wahala bi ayẹyẹ igbeyawo oun ṣe n sunmọ etile.
"Eto ayẹyẹ igbeyawo mi lo wa lori ẹmi mi bayii. Ki n maa lọ jẹjẹ mi ni bayii, ati pe lẹyin naa, ki n japa," Peller fi kun ọrọ rẹ.
Ki lo gbe Peller de ahaamọ ọlọpaa
Laipẹ yii ni ọmọkunrin naa gbe fọnran ibi to ti n ba awọn ọlọpaa ni faakaja sori ikanni ayelujara, nibi to ti fẹsun kan wọn wi pe wọn da oun duro lọna aitọ, wọn si tun n fi ibọn dẹru ba oun.
Peller sọ pe oun ṣẹṣẹ ra ọkọ tuntun ti wọn n beere nọmba rẹ lọwọ oun, ati pe wọn n ba oun ṣe iwe ọkọ naa lọwọ.
Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni wọn foju Peller ba ile-ẹjọ, pẹlu akẹgbẹ rẹ, Bello Oladipo lori ẹsun mẹta ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu didi ọlọpaa lọwọ iṣẹ wọn, ṣiṣẹ ohun to le da alaafia ilu laamu ati igbimọ lati huwa ipa.
Ile-ẹjọ Majisireeti ti Peller foju ba ti wa sọ pe ki wọn gba beeli rẹ pẹlu idaji miliọnu kan naira, lati f'opin si ọjọ to ti lo lahaamọ ọlọpaa.




























