You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jàndùkú kọlù òṣìṣẹ́ EFCC tó ń tọ̀pinpin ìbò ní Abuja àti Imo
Ajọ to gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede yii (EFCC) kede pe awọn afurasi janduku kan kọlu awọn osisẹ oun, to n lọ kiri lati mojuto bi eto idibo ṣe n lọ ni Abuja ati nipinlẹ Imo.
Ninu atẹjade ti ajọ EFCC fi soju opo ayelujara Twitter rẹ ni ikọlu naa waye lọjọ Satide Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu keji ni agbegbe Bwari niluu Abuja.
O ni awọn osisẹ naa ni wọn kọlu lẹyin ti wọn mu ọkunrin kan to n fi owo ra ibo nibi eto idibo ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni Bwari.
Awọn osisẹ EFCC naa ni wọn fi ofin mu ọkunrin naa, ẹni ọgbọn ọdun, ti wọn si sawari iye awọn eeyan to ti fun lowo lati ra ibo wọn lori ẹrọ ile ifowopamọ rẹ.
Asiko ti wọn gbe afurasi naa kuro nibi eto idibo ni awọn afurasi janduku ṣe ikọlu si ọkọ Ajọ EFCC, ti wọn si bajẹ.
Awọn osisẹ Ajọ EFCC sina bolẹ, ti awọn afurasi naa si sawọ ninu igbo.
Lẹsẹkẹsẹ ni ajọ EFCC fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti iwadi si ti bẹrẹ.
Bakan naa ni awọn afurasi janduku miran tun kọlu awọn osisẹ EFCC nipinlẹ Imo, ti wọn si tun sinabolẹ fun awọn osisẹ naa nibi ti eto idibo ti n waye ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Mann ni agbegbe Chorobim.
Awọn osisẹ kọlu awọn afurasi janduku naa lẹyin ti wọn kẹfin pe wọn n fi owo ra ibo ni agbegbe naa.
Bawo ni igbaradi ajọ EFCC ṣe ri?
Ikọ aṣewadii ajọ naa ti wa nikalẹ kaakiri gbogbo ipinlẹ ati olu ilu orilẹede Naijiria tii ṣe Abuja.
Bakan naa, awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ pajawiri ti wa ti wọn pin kaakiri ori ayelujara fun awọn araalu lati pin iroyin tabi ta wọn lolobo lori gbogbo magomago to ba nii ṣe pẹlu ajọ EFCC. Wọn ni ẹkunrẹrẹ awọn nọmba yii wa loju opo ayelujara EFCC.
Wọn ti wa rọ awọn araalu lati fi ẹjọ ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati ra tabi ta ibo pe ki wọn lo awọn oju opo ifẹjọsun ti EFCC ti wọn n pe ni “EFCC financial reporting APP ati “Eagle Eye” eyi ti wọn lee gba sori ẹrọ̀ wọn latori oju opo ayelujara Google Play tabi Apple Store.
Bakan naa ni ajọ EFCC ni ẹnikẹni lee kan si awọn loju opo ikansiraẹni facebook wọn.
Báyìí ni àjọ EFCC ṣe rí N32.4m owó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan fẹ́ fi ra ibò l’Eko gbà
Akitiyan ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC ti bẹrẹ si bimọ ire lonii latari ati gbogun ti katakara atawọn mọkaruru to nii ṣe pẹlu owo ṣaaju idibo ipo aarẹ ati ti ile igbimọ aṣofin ti yoo waye lọla.
Iṣẹ ti yaa bẹrẹ fun wọn naa niyẹn o gẹgẹ bi wọn ṣe fi panpẹ ọba gba owo to to miliọnu mẹtalelọgbọn o le ẹgbẹrun lọna irinwo naira ti wọn fẹsun kan wipe rira ibo ni wọn fẹ fi ṣe ni ipinlẹ Eko.
Awọn oṣiṣẹ ẹka ajọ EFCC to wa ni ipinlẹ Eko naa lo ṣe kongẹ gbigba owo naa wọn si ti ko awọn afurasi to lọwọ ninu ẹsun naa si atimọle fun ifọrọwanilẹnuwo.
Alaga ajọ EFCC, Abdulrasheed Bawa ti rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti wọn ran lati ṣiṣẹ lasiko idibo yii pe ki wọn ni igboya ki wọn si ma faaye gba awọn onimọndaru tabi oniwa to lodi si ofin lati ta epo si aṣọ ala eto idibo nipasẹ fifi owo ra ibo.
Ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ tó ń pín ẹ̀bùn tàbí tó ń gba ẹ̀bùn owó fi ra ìbò yóò ṣẹ̀wọ̀n-EFCC
Alaga ajọ to gbogunti iwa ibajẹ lorilẹede yii (EFCC) Abdulrasheed Bawa kede pe awọn oloṣelu ti setan lati ra ibo pelu owo naira atijọ ki wọn si tun pin ẹbun ni ibi ti eto idibo yo ti waye.
Bawa sọro yii nigbati oun dahun ibere lori igbaradi ajọ rẹ fun eto idibo ọdun yii.
Alaga ajọ EFCC fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn osiṣẹ ajọ naa ni wọn ti fi sọwọ si awọn gbagede ti eto idibo yoo ti waye kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa ni Orilẹede yii to fi mo olu ilu Abuja Bawa rọ awọn ọmọ orilẹede yii lati sọrọ soke ti wọn ba kẹfin iwa ibajẹ nibiti wọn ti n dibo wọn.
Bawa ni”ajọ EFCC ti ri ẹri to daju pe ọpọlọpọ awọn oloṣẹlu lo ti ra awọn ohun ti wọn fẹ pin nibi ti awọn eeyan ti fẹ dibo lati ra ibo wọn.
"Awọn oṣiṣẹ ijọba,awọn gomina lo fe fowo ra ibo"
O ni ajọ oun ti ṣetan lati fi pampẹ ofin mu ẹnikẹni ti ọwọ awọn oṣiṣẹ EFCC ba tẹ ti wọn fi ẹbun ra ibo lọwọ awọn eeyan”.
Bawa fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ijọba,awọn onisowo ti wọn kudun iwa ibajẹ ati awọn gomina ni awọn ipinlẹ kọkan ni wọn ti ko owo naira tuntun ati tatijọ pamo lati fi ra ibo ninu eto idibo aarẹ ọdun yii.
Alaga ajọ EFCC ni gbogbo ọgbọn arekereke awọn to fẹ wuwa ibajẹ lọjọ idibo ni awọn mo ti ajọ EFCC ti gbaradi lati fofin mu ẹnikẹni ti ọwọ ajọ ohun ba tẹ.
Bawa rọ awọn ọmọ orileẹde yii lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn osiṣẹ ajọ EFCC lati gbogun ti iwa ibajẹ.