Ṣé ọmọ bíbí lè dín iye ọjọ́ tó yẹ kí obìnrin lò lókè eèpẹ̀ kù?

    • Author, Kate Bowie
    • Role, Global Health, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ti awọn ọmọde ba n ṣe ijọgbọn tabi ti wọn ba kọ lati jẹun, awọn obinrin kan a sọ pe awọn ọmọ naa n din iye ọjọ awọn gẹgẹ bii obi ku.

Iwadii tuntun kan ti fi han pe eyii ko jina si ootọ, paapaa fun awọn obinrin ti iya n jẹ.

Koda, nnkan bii oṣu mẹfa gbako lo le dinku ninu aye awọn obinrin mii fun ọmọ kọọkan ti wọn ba bi, paapaa fun awọn obinrin to n gbe ninu inira.

Lasiko ti iyan ja ni Finland laarin ọdun 1866 si ọdun 1868, awọn oluwadii ṣewadii obinrin 4,684.

Ọmọwe Euan Young lati fasiti Groningen lorilẹede Netherlands atawọn ikọ rẹ, Ọjọgbọn Hannah Dugdale, Ọjọgbọn Virpi Lummaa aati Ọmọwe Erik Postma sọ pe iyan naa lo buru julọ ninu itan ile Yuroopu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn obinrin ti wọn bimọ kasiko iyan naa ni oṣu mẹfa ge kuro lara iye ọjọ to yẹ ki wọn lo loke eepẹ lori ọmọ kọọkan ti wọn n bi.

Iwadii naa fi han pe eyii le ri bẹẹ latari pe awọn obi naa n lo agbara to pọ lati tun awọn sẹeli inu ara wọn ṣe, eyii to fi wọn sinu ewu kiko awọn arun lọjọ iwaju.

Ṣugbọn wọn ko ri aridaju iye ọjọ ti awọn obinrin n lo ati bi wọn ṣe n bi ọmọ si ṣaaju iyan naa.

Ikọ oluwadii naa fidi rẹ mulẹ pe agbegbe ti awọn obinrin naa n gbe lasiko ti wọn n bimọ ni nnkan lati pẹlu esi iwadii ọhun.

Ki ni idi ti ọmọ bibi fi n ni ipa lori asiko obinrin loke eepẹ?

Nitori naa, ki ni idi to fi ri bẹẹ?

Alaye akọkọ ni pe ipa ti ọmọ bibi n ni lara obinrin le buru si latari inira ti irufẹ obinrin naa n koju lagbegbe to n gbe.

Kii ṣe tuntun pe awọn iya wa wa ninu awọn ewu aisan bii aisan ọkan latari bi wọn ṣe n sanra si atawọn wahala mii ti wọn n ṣe.

Ọmọwe Young sọ pe wahala ti awọn obinrin maa n ṣe lasiko ti wọn ba n fun ọmọ lọyan atawọn wahala mii maa n din iye agbara obinrin to bimọ ku.

Ipo iloyun ati fifun ọmọ loyun maa n gba ọpọ agbara lara obinrin, to n tumọ si pe awọn obinrin yoo padanu ọpọ agbara wọn lasiko ti iyan ba n mu.

Young sọ siwaju si pe ti obinrin ba n bimọ leralera lai ni isinmi to yẹ, o le ṣakoba fun ilera irufẹ obinrin bẹẹ.

Ṣe nnkan yii n ṣẹlẹ si awọn obinrin laye ode oni?

Amọ ṣa, ṣe ohun to pa awọn obinrin lara ni igba ọdun sẹyin le maa pa awọn obinrin lara laye ode oni?

Young ni 'ti a ba fi oju ṣunukun wo ọrọ yii, a maa ṣakiyesi pe eto ilera to wa lode oni ko si laye atijọ.

"Laye igba naa, awọn obinrin n bi ọmọ bii mẹrin si marun un lọ, eyii ti ko ri bẹẹ laye ode oni."

Lati ọdun 1800 lawọn obinrin ti n din iye ọmọ ti wọn n bi ku kaakiri agbaye.

Lọdun 2023, pupọ obinrin ni ko bi ju ọmọ meji pere lọ, eyii to jẹ ayipada to n waye lataro ọlaju ati bi awọn eeyan ṣe n kawe si.

Amọ awọn orilẹede kan wa bii Niger, Chad, Somalia ati South Sudan ti awọn obinrin ṣi n bimọ bẹẹrẹ.

Lọdun to kọja si ni wọn kede iyan ni Sudan ati Gaza eyii ti yoo tunbọ mu ki aye le koko fun awọn obinrin to wa nibẹ.