You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹni tí wọn ò bá bú tó ń bú èèyàn ni Peter Obi- Sanwo-Olu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti bu ẹnu atẹ lu Peter Obi, gomina Anambra tẹlẹ to dije ipo aarẹ Naijiria ni 2023 ninu ẹgbẹ oṣelu Labour.
Ninu atẹjade kan ti Gomina Sanwo-Olu fi sita lọjọ Aiku lo ti ni Peter Obi ko yẹ lẹni to yẹ ko maa sọrọ abuku si aarẹ to n ṣelu lọwọ, ati awọn olori to ti kọja.
Sanwo-Olu sọ pe ẹni ti wọn ko ba bu nitori iwa ajẹbanu rẹ ni Peter Obi, ṣugbọn oun lo waa n bu awọn ẹlomi-in to n gbiyanju fun Naijiria.
Kí ni Peter Obi sọ?
Peter Obi rin irinajo lọ si orilẹede America, Yunifasiti Hopkins lo si ti sọrọ to pada di ohun ti Sanwo-Olu n fun un lesi yii.
Peter Obi sọ pe ijọba to wa lode yii n ko ba ọrọ aje Naijiria pupọ, bẹẹ ni wọn n mu ìṣẹ́ ati òṣì pọ si i.
Nigba ti Sanwo-Olu n fun un lesi, o ni:
" B'awọn eeyan nla ni Naijiria ba de oke okun, ọrọ to le gbe Naijiria ga lo yẹ ki wọn sọ, ki i ṣe eyi ti yoo jẹ ki ilu naa di nnkan ikorira" .
"Ijọba kọ ni wọn n ṣe e fun ti wọn ba ṣe bẹẹ, gbogbo wa lo yẹ ka jọ patẹ Naijiria lọja agbaye, ki i ṣe ka maa fẹnu tabuku rẹ.
" Ọrọ Ọgbẹni Obi tiẹ jọ mi loju, Obi ti ko kọ ileewe kan ṣoṣo tabi ileewosan titi to fi pari ọdun mẹjọ l'Anambra.
"Ko pese aaye idẹrun fun araalu ẹ, oun lo waa n bu ẹni to n fi gbogbo ara ṣe atunṣe.
"Ki Peter Obi too di gomina Anambra lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa ọdun 2007, Ìṣẹ́ ati òṣì to wa nibẹ jẹ ida mọkanlelogoji ati mẹrin (41.4%).
"Ṣugbọn lẹyin ọdun meji pere lọfiisi, iṣẹ ati òṣì Anambra fo soke wọ 53.7%.
"Ẹni to gba ipo lẹyin Obi, Willie Obiano, din iṣẹ ati oṣi ku si 14.8% lẹyin ọdun marun-un, nigba to ti fẹẹ wọ ida ọgọta 60%.
"Obi da kun ìṣẹ́ àti òṣì ni Naijiria ni.
"Nigba toun n ko Naijiria si ìyà ni Tinubu to jẹ gomina Eko nigba naa n mu miliọnu eeyan jade ninu òṣì.
"Ta lo wa yẹ ko maa bu ara wọn ninu ọrọ to wa nilẹ yii?" Bẹẹ ni Sanwo-Olu beere ibeere to pesi jẹ ọhun.