Ìjọba kò rán òṣìṣẹ́ FRSC kankan láti lọ máa fi ipá mú mọ́tò lójú pópó - Major Salawu tó dá FRSC sílẹ̀

Ìjọba kò rán òṣìṣẹ́ FRSC kankan láti lọ máa fi ipá mú mọ́tò lójú pópó - Major Salawu tó dá FRSC sílẹ̀

Ni ọdun 1977 ni Ọgagun kan fi iṣẹ ologun silẹ laipe ọjọ. Eyi si ya ọpọlọpọ awọn ọgba ati ọga rẹ lẹnu nitori wọn ri i nigba naa gẹgẹ bi ẹni to ni ọjọ ọla rere lẹnu iṣẹ ologun nigba naa.

Major Rasaki Ọlalekan Alamu Salawu fi iṣẹ ologun silẹ lati le ala rẹ nipa abo loju popo lorilẹede Naijiria.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Major Salawu woye pe nibi idanilẹkọ ologun ti oun lọ fun ni okeokun loun ti kẹkọọ nipa ọrọ amojuto ọkọ loju popo.

Eyi lo ba gomina ologun ni ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Ọgagun Jẹmibẹwọn si tẹwọ gba iran to ni naa oun ni wọn fi bẹrẹ ajọ naa ni ipinlẹ Ọyọ nigba naa.

Alagba Salawu to ṣalaye bi araalu ṣe sọ ajọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Road safety ni ibẹrẹ pẹlpẹ di 'Majamaja' sọ pe oṣelu lo mu ki wọn daw rẹ duro nigba naa ki o to di wi pe ijọba ologun labẹ Ọgagun Babangida tun ranṣẹ pe oun lati tun bẹrẹ rẹ fun ijọba apapọ lọdun 1987.

Ijọba ko ran oṣiṣẹ FRSC kankan lati fi ipa mu ọkọ duro

Nigba to n sọrọ lori awọn ihuwasi oṣiṣẹ FRSC lawọn oju popo kaakiri Naijiria bayii, Alagba Salawu ṣalaye pe ko si ninu iwe ofin idasilẹ ajọ naa pe ki wọn maa fi ipa mu awọn ọkọ duro loju popo.

"Ko si ijọba kankan ti yoo ran ẹṣọ oju popo niṣẹ pe bi ko ba duro ki ẹ jọ maa du kọ."

O ni mimu nọmba ni ọna ọmọluwabi ti ofin la kalẹ.