'Ojú ọkọ mi tó fọ́ ló sọ mi di ọlọ́kadà'

'Ojú ọkọ mi tó fọ́ ló sọ mi di ọlọ́kadà'

Nigba ti Arabinrin Mary Daniel ji nibẹrẹ aye rẹ, ko mọ pe iṣẹ ọkada ni oun yoo ma a ṣe, amọ iriri aye ti sọ ọ di ọlọkada bayii.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Arabinrin Daniel to n gbe niluu Ado-Ekiti, sọ pe ọkọ oun lo kọkọ n ṣe iṣẹ ọkada naa, amọ oju rẹ kan to fọ ni ko jẹ ko le ṣe iṣẹ naa mọ.

O ṣalaye pe nigba ti ọkunrin naa wa ni ọdọ lo kọkọ ni aisan catarract ninu oju rẹ.

Ẹnu iṣẹ ọkada gigun ni aisan naa ti buru ju bo ṣe yẹ lọ, ti oju kan si fọ patapata.

Eyi lo mu ki iyawo pinnu lati ma a ṣe iṣẹ naa nitori ki ebi o ma ba pa oun, ọkọ ati awọn ọmọ mẹrin ti wọn bi.

Ṣaaju ki eyi to o ṣẹlẹ ni tọkọtaya naa n ṣe ọsin adiyẹ ati okowo miran, amọ ọna to daru naa lo sọ ọkọ di ẹni to n gun ọkada.

Arabinrin Daniel sọ pe ọpọ eeyan lo ma n sọ ọrọ buruku ati eebu nipa ọkọ oun.

"Ti wọn ba beere pe ọkọ mi nkọ, ti mo si sọ fun wọn pe o wa nile, awọn mi a sọ pe oponu ni.

"Ṣugbọn eeyan melo ni mo fẹ ma a sọ fun pe oju ọkọ mi ti fọ, ohun lo si sọ mi di ẹni to n gun ọkada?"

Obinrin naa ṣalaye pe eeyan kan ti họ kẹlẹbẹ si oun loju ri nibi ti oun ti n gun ọkada, eyi to sọ ọjọ naa di ọjọ ibanujẹ fun oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iṣẹ ọkada gigun naa ko rọrun rara, ṣugbọn owo ti oun n ri nibẹ ni oun fi pese ounjẹ, san owo ile ati ile ẹkọ.