You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Mo pàdánù ọmọkùnrin méjì, ọkọ àtàwọn ẹbí mi míì, ọmọ mẹ́tàlá ni ọkọ mi sílẹ̀ fún mi"
- Author, Abubakar Maccido
- Role, Reporter
- Reporting from, Kano
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
"Mo pàdánù ọmọkùnrin méjì, ọkọ àtàwọn ẹbí mi míì, ọmọ mẹ́tàlá ni ọkọ mi sílẹ̀ fún mi".
Èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu arábìnrin Faji Sani tó pàdánù ọkọ rẹ̀, ọmọ méjì àtàwọn ẹbí míì sọ́wọ́ ìkọlù táwọn èèyàn kan ṣe sí àwọn arìnrìnàjò kan ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Arábìnrin Sani ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú àwọn èèyàn rẹ̀.
Ìpànìyàn tó wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Mangu ní ìpínlẹ̀ Plateau ní ọjọ́ Ẹtì tó kọjá yìí, níbi tí àwọn aráàlú Mangu ti dáná sun ọkọ̀ àwọn arìnrìnàjò ti ń fa onírúurú awuyewuye ní Nàìjìríà.
Àwọn arìnrìnàjò náà ló ń lọ síbi ètò ìgbéyàwó ní ìjọba ìbílẹ̀ Qua'an Pan ní ìpínlẹ̀ Plateau láti ìlú Zaria, ìpínlẹ̀ Kaduna káwọn èèyàn kan tó dáwọn dúró ní Mangu tí wọ́n sì ṣe ìkọlù sí wọn.
Lára àwọn èèyàn náà pàdánù ẹ̀mí wọn síbi ìkọlù náà lójú ẹsẹ̀ nígbà táwọn míì farapa, tí wọ́n sì ti wà nílé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú báyìí.
Àwọn aláṣẹ sọ pé èèyàn mẹ́tàlá ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà tó sì júwe ìwà táwọn èèyàn náà hù bíi ìwà ìkà àti ọ̀dájú, tó sì tẹnumọ pé kò yẹ káwọn èèyàn tó ṣiṣẹ́ ibi náà lọ láì jìyà.
"Kò sí ìdí tí èèyàn kan gbọdọ̀ ṣe ìkọlù sí ọmọ Nàìjíríà míì ní ibikíbi ní orílẹ̀ èdè yìí", Gómìnà Sani sọ fún BBC Hausa.
Bákan náà ló sọ fún akẹgbẹ́ rẹ̀ ní Plateau, Gómìnà Caleb Mutfwang pé kó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti rí i dájú pé, ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ìkọlù náà.
"Mo máa tẹ̀lé ìwádìí náà fúnra mi. A gbọdọ̀ fi hàn pé a ò ní gba irúfẹ́ ìwà báyìí láàyè mọ́," ó sọ.
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu náà ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù ọ̀hún, tó sì sọ pé àwọn kò ní fi ààyè gba ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí.
Ààrẹ ní káwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ri dájú pé ọwọ́ òfin tẹ àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà, kí wọ́n sì ri pé wọ́n fojú winá òfin.
Ó fi kun pé ẹ̀tọ́ ọmọ Nàìjíríà ni láti lè rìn ní ibikíbi tí ẹnikẹ́ni kò lè gbà. "A ò ní gbà kí ẹnikẹ́ni tàbí ẹgbẹ́ kan fi ìwà ipá tàbí ìbẹ̀rù láti fi dènà àwọn èèyàn láti máa rìn sí ibi tó wù wọ́n."
Kí ni ṣíṣekúpa àwọn arìnrìnàjò ní Plateau túmọ̀ sí fún ṣíṣe ìrìnàjò ní Nàìjíríà?
Ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò ní ìpínlẹ̀ Plateau yìí ti ń mú káwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ nípa ààbò tó wà fáwon èèyàn láwọn òpópónà pàápàá jùlọ bó ṣe jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ ń wáyé.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù díẹ̀ táwọn èèyàn kan ṣe ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò kan tó jẹ́ ọdẹ tí wọ́n ń lọ fọdún ìtúnu ààwẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Rivers lọ sí ìpínlẹ̀ Kano.
Ní ìlú Uromi ní ìpínlẹ̀ Edo ni ìkọlù náà ti wáyé tí wọ́n sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn.
Lọ́dún 2018, ọ̀gágun kan tẹ́lẹ̀ rí lẹ́nu iṣẹ́ ológun, Mohammed Idris Alkali di àwátì nígbà tó ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Bauchi láti Abuja. Òkú rẹ̀ ni wọ́n padà ṣàwárí ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Ohun tó jẹ́ nǹkan tó ń kan èèyàn lóminú báyìí nip é yàtọ̀ sáwọn agbébọn àti ajínigbé tó ń pa àwọn èèyàn tàbí jí èèyàn gbé láwọn òpópónà, ó ṣeéṣe kí èèyàn tún kó sọ́wọ́ àwọn tí yóò lu èèyàn pa láì ṣẹ̀ wọ́n.
'Nítorí pé kìí sí ìjìyà fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ láabi yìí ló ṣe ń pọ̀ si'
Àwọn èèyàn kan wòye pé ìpànìyàn tó ń wáyé sáwọn arìnrìnàjò láwọn òpópónà kò ṣẹ̀yìn àìsí ààbò tó péye tó ń bá Nàìjíríà fínra àti báwọn agbébọn àti darandaran ṣe ń yawọ ìlú tí wọ́n sì ń ṣe ìkọlù sí wọn.
Àmọ́ onímọ̀ nípa èètò ààbò kan tó fi ìpínlẹ̀ Borno ṣe ibùjókòó, Auwal Bala gbàgbọ́ pé ìdí táwọn èèyàn tó ń ṣe ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò ṣì ń tẹ̀síwájú ni pé àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn kò kojú ìjìyà kankan.
Ó sọ fún BBC News Pidgin pé àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní ìdí kan tàbí òmíràn yálà nípa òṣèlú, ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n fi ń ṣe é.
"Àwọn kan ń ṣe é nítorí òṣèlú, ẹ̀sìn, àtì ẹ̀yà àmọ ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò sí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pa èèyàn bẹ́yẹn kódà bó jẹ́ pé onítọ̀hún ṣẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára," Bala sọ.
Ó fi kun pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí, kò yẹ káwọn èèyàn máa ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.
"Ẹ ò kàn lè máa gbẹ̀mí lọ́rùn àwọn èèyàn nítorí agbègbè yín ń kojú àìsí ààbò, ó yẹ kí wọ́n ṣe ìwádìí nípa ẹni táwọn èèyàn náà jẹ́ ná ni.
"Kódà kó jẹ́ pé afurasí ni wọ́n, ó yé kí wọ́n kó wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tàbí àwọn aláṣẹ, kò yẹ kí wọ́n lo àìsí ààbò gẹ́gẹ́ bí ohun ìkẹ́wọ́," ó sọ.
Kí ni ọ̀nà àbáyọ?
Onímọ̀ nípa ààbò náà sọ pé ọ̀nà kan gbòógì láti dènà ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò ni tí ìjọba àti ilé ẹjọ́ bá bẹ̀rẹ̀ sí ní fìyà jẹ àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú rẹ̀ láì fi ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn ṣe.
Dókítà Bala sọ pé ẹni tí ọwọ́ bá ti tẹ̀ lórí irú ìwà báyìí, níṣe ló yẹ kí wọ́n gbé ẹni lọ sílé ẹjọ́ láti kojú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
"Kí wọ́n má fi ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà bọ inú rẹ̀ rárá. Ìka tó bá ti ṣẹ̀, kí ìjọba ge ni.
"Káwọn adajọ́ náà má fi ẹ̀lẹ̀ mú irú ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, kí ìjìyà tó lágbára wà fún, káwọn míì le ti ara bẹ́ẹ̀ kọ́gbọ́n láti má hu irú ìwà bẹ́ẹ̀."