'Láti 2021 tí Amotekun yìnbọn bá mi, ìjọba ẹ ṣàánú mi, mò ṣì ń réti 30M tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kẹ́ẹ fún mi'

'Láti 2021 tí Amotekun yìnbọn bá mi, ìjọba ẹ ṣàánú mi, mò ṣì ń réti 30M tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kẹ́ẹ fún mi'

"Mo ti lọ si ọfiisi ijọba, mo ti lọ "human affairs", mo ti para ọfiisi awọn Amotekun to yin mi nibọn naa, ẹrin ni wọn n fi mi rin".

Eyi wa lara ọrọ ti Oluwasegun ba BBC Yoruba sọ nigba to n ṣalaye aduru irora ati iya to ti jẹ lori ẹsẹ rẹ to si n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ondo lati tete ṣaanu oun gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe pa wọn laṣẹ.

Olusegun Oluwarotimi to jẹ ọlọkada ṣalaye pe oun ni lati ta ọkada ti oun fi n ṣowo ni lati le tete tọju ara rẹ na nigba ti ikọ Amotekun to yinbọn ba a lẹsẹ ninu oṣu kẹjọ ọdun 2021 kọ lati gbọ bukata titọju ẹsẹ naa.

"Mo ti lọ si ọfiisi gomina, wọn o gbọ temi. Awọn eeyan gba mi nimọran pe ki n lọ si ọfiisi awọn to n ri si ọrọ ọmọniyan mo tun lọ, asan lẹta ni wọn kọ titi ti a ko ri esi.

Olusegun ni gbogbo igba ti oun ati iya oun tun lọ sunkun niwaju ọfiisi awn ikọ Amotekun, ẹrin ni wọn fi awọn rin ti wọn ni ki oun lọ kọwe pe eṣiṣi ni ibọn naa fi ba oun lasiko ti awọn Fulani ati ikọ Amotekun kọlu ara wọn.

Amọ Olusegun ni ounkọ lati pa irọ yii titi ti o fi ri agbẹjọro ẹlẹyinju aanu kan Tope Komokun ti awọn eeyan ni ki oun lọ ba.

Ija ti agbẹjọro naa ja fun Olusegun lo mu ki ile ẹjọ pada dajọ pe ki ati ijọba ipinlẹ Onodo ati ikọ Amotekun ki wọn san owo to to miliọnu ọgbọn fun un.

Amọ titi di akoko yii, Olusegun ko tii ri owo naa gba fi tọju ara rẹ.