Àwọn agbébọn ṣekúpa DPO àti ọlọ́pàá mẹ́rin mìíràn ní Niger

Awọn agbebọn ti ṣekupa Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ọmọ ẹyin rẹ mẹrin ni agbegbe ijọba ibilẹ Munya ati Gurara nipinlẹ Niger.

Awọn oloogbe naa lo gbẹmimi nigba ti wọn gbe ibọn koju awọn agbebọn naa to ṣekọlu si agbegbe naa.

Wasiu Abiodun, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa fidi isẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ Aiku.

O salaye pe awọn ọlọpaa gbinyanju lati koju awọn agbebọn naa ninu ọga kan ni ijọba ibilẹ Munya lọjọ Ẹti, ti wọn si tun koju awọn miiran lọjọ Satide nijọba ibilẹ Gurara.

Abiodun darukọ DPO naa gẹgẹ bi Mukhtar Sabiu to jẹ ọga agba fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Paiko.

Bakan naa ni ko darukọ awọn ọlọpaa mẹrin yooku.

“Pẹlu ibanujẹ ọkan ni afi kede iku DPO, Mukhar Sabiu ati awọn ọlọpaa mẹrin ti wọn padanu ẹmi wọn nigba ti wọn koju awọn agbebọn.

“Isẹlẹ naa waye lọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023 nigba ti awọn agbebọn ṣekọlu si abule Chibani to wa Sarkin- Pawa ni ijọba ibilẹ Munya.

“Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lati Gawu-Babangida ati Paiko, awọn ọmọ ologun ati figilante ni wọn lọ koju awọn agbebọn naa, ti wọn si wọ iyaja, ti ọpọ agbebọn naa si farapa.”

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, Kọmisọna ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Ogundele Ayodele ṣe abewo si ibi isẹlẹ naa, ti wọn si ti ri oku awọn ọlọpaa to ba isẹlẹ naa lọ.

Nigba to ṣe abẹwo si awọn mọlẹbi oloogbe naa, Kọmisọna fi da awọn mọlẹbi loju pe idajọ ododo yoo waye lori isẹlẹ naa.