Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Niṣe ni ọrọ di bo o lọ o ya fun mi ni ilu Agenebode, ipinlẹ Edo lọjọ Aiku
Ki lo ṣẹlẹ nibẹ ẹ?
Awọn ọdọ kan ma lo dana sun agọ ọlọpaa atawọn ọkọ niluu naa
Lati fẹhonuhan lẹyin ti wọn ṣawari eegun awọn eeyan ni agbala olori agbegbe ọhun
Ṣe ẹ fẹ mọ bi aṣiri ṣe tu?
Ẹ kan soju opo BBC News Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
Akọni eeyan ni ọmọ ọ mi, Zeenat Balogun ko to jade laye
Gbajumọ oṣere tiata nni, Saidi Balogun lo fohun akọni sọrọ bẹẹ lẹyin iku ọmọbinrin rẹ
Atẹjade ti ilumọọka oṣere naa fi sori ikanni rẹ lọjọ Aiku lo fi ki tẹbi tara ati ọrẹ ti wọn ba a kẹdun lori iku ọmọ naa
Lọjọ Ẹti, ọjọ Karun-un, oṣu Kẹwaa ni Zeenat jade laye lẹyin aisan ranpẹ
Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti dunkoko lati ma kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fẹ gba lọla ọjọ Iṣẹgun pẹlu Libya
Latari wi pe wọn dawọn duro si papakọ ofurufu niluu ilu Al Abraq lana ọjọ Aiku lai si ounjẹ tabi ibi wọn le sun si
