Ohun tí ìjọba Qatar sọ rèé nípa físà fún àwọn ọmọ Naijiria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹdee Qatar ti sọ pe irọ ni iroyin to n milẹ titi pe oun ti gbẹsẹle fisa fun awọn ọmọ Naijiria.

Aṣoju ẹka ti wọn ti n gbe fisa jade nilẹ naa sọ fun BBC pe ko si ofin kankan ti wọn fi de awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ ṣabẹwo silẹ naa lọwọ yii.

Ṣaaju ni oniruru auwyewuye ti kọkọ n lọ lori itakun ayelujara ni Naijiria nibi ti awọn eeyan ti n sọ pe Qatar ti fofin de Naijiria.

Lara awọn ohun ti awọ eeyan n sọ ni pe Qatar ko ni maa fun awọn ọkunrin ni fisa, ayafin awọn obinrin nikan, tabi awọn ọkunrin to ba fẹ wọlẹ silẹ naa pẹlu awọn mọlẹbi wọn nikan.

Awọn eeyan tun n sọ pe awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ si Qatar gbọdọ ti san owo ile itura olowo nla " 5-Star' silẹ ki wọn to lọ, to fi mọ tikẹẹti ti wọn yoo fi pada si Naijiria ki wọn to wọ Qatar.

Wayi o, ijọba Qatar ti fidi rẹ mulẹ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.

Nibo ni iroyin ofege akọkọ ti wa?

Iroyin to kọkọ sọ nipa awọn ofin tuntun yii lo wa lati ọdọ ileeṣẹ 'Discover Qatar' to jẹ ileeṣẹ kan ni Qatar amọ to n ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ arinrinajo ilẹ okere ni Naijiria.

Atẹjade ileeṣẹ naa sọ pe eredi igbeṣe ọhun ko ṣẹyin bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe maa pẹ ju akoko ti wọn sọ pe awọn yoo lo ni Qatar lọ.

Wayi o, ẹka to n pin fisa nileeṣẹ ijọba Qatar ti sọ fun BBC pe awọn ṣi n fun awọn ọmọ Naijiria ni fisa bi wọn ṣe n tẹlẹ lai si wahala kankan.

Wọn ni "Ko si ofin ti a fi de Naijiria tabi ayipada kankan, ti a ba maa gbe igbesẹ kankan a o kede rẹ lawọn oju opo wa."

Lati bii ọdun mẹra sẹyin lawọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n rininajo lọ si Qatar eyii ti awọn onimọ kan sọ pe ko ṣẹyin ede aiyede to waye laarin Naijiria ati ilẹ United Arab Emirates, UAE, laarin ọdun 2021 si 2024.

Yatọ si pe awọn ọmọ Naijiria maa n gba Qatar lọ si awọn ilẹ mii bii Europe ati Asia, wọn ti n gbe, wọn si ti n ṣiṣẹ nibẹ pẹlu.

Koda, awọn ọmọ Naijiria kan ti n lọ si n Qatar pẹlu erongba lati lọ ṣe igbeyawo wọn nibẹ.