You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá ọmọ Nàìjíríà sọ ní àyájọ́ òmìnira
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti kan sáárá sí àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní àyájọ́ òmìnira bí Nàìjíríà ṣe pé ọdún márùndínláàádọ́rin tó gba òmìnira.
Tinubu sọ pé Nàìjíríà ti la àwọn ìgbà tó le kọjá àti pé àsìkò láti máa jẹ àwọn ọrọ̀ ìyà tí a ti jẹ sẹ́yìn ti dé báyìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ìṣèjọba ti gbéṣe lẹ́nu ìgbà tó ti wà nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà.
Ó ní gbogbo ọmọ Nàìjíríà ló nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ri pé gbogbo àwọn àṣeyọrí so èso rere àti pé ìjọba àpapọ̀ yóò máa tẹ̀síwájú láti ri pé ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà dúró ire.
Ètò ọrọ̀ ajé
Tinubu ní lóòótọ́ ni àwọn kan máa ń wòye pé ibìkan ló yẹ kí Nàìjíríà wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè àmọ́ ààrẹ ní ibi tí Nàìjíríà wà lórí ọrọ̀ ajé nígbà tó gba òmìnira kọ́ ló wà báyìí.
Ààrẹ ní ìyàtọ̀ ti bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gidi lòdì sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀ ní ọdún márùndínláàádọ́rin ọdún sẹ́yìn.
Ó sọ pé lábẹ́ ìṣèjọba òun, ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ni àdínkù ti bá pẹ̀lú ìdá ogún nínú oṣù Kẹjọ ọdún yìí èyí tó kéré jùlọ láàárín ọdún mẹ́ta tí òun ti gba ìjọba.
Ó fi kun pé àwọn ń ṣiṣẹ́ láti ri pé ìgbéga bá ètò ọ̀gbìn lójúnà àti mú kí oúnjẹ pọ̀ yanturu àti láti mú àdínkù bá owó oúnjẹ.
Ó tẹ̀síwájú pé àlékún ti ń bá bí wọ́n ṣe ń pawó wọlé láì gbé ara lé owó epo rọ̀bì èyí tó wọ ogún tírílíọ̀nù náírà ní ọdún 2025 nìkan.
Bákan náà ló fi kun pé owó tí àwọn ń pa wọlé lòdì sí èyí tí wọ́n fi ń san gbèsè ni àdínkù ti bá jọjọ.
Ààrẹ ní Nàìjíríà ti ń kó ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè púpọ̀ báyìí yàtọ̀ sí epo rọ̀bì nìkan dípò bó ṣe jẹ́ pé Nàìjíríà ló máa ń gbé ara lé ọjà tí wọ́n ń kó wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè bó ṣe rí tẹ́lẹ̀.
Ètò ẹ̀kọ́
Tinubu wòye pé ìgbéga ti bá ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà yàtọ̀ sí bí ó ṣe wà ní ọdún 1960 tí Nàìjíríà gba òmìnira.
Ó ní ọgọ́fà (120) ilé ẹ̀kọ́ girama ló wà ní Nàìjíríà lọ́dún 1960 ṣùgbọ́n tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ girama tó wà ní Nàìjíríà báyìí ti lé ní 23,000 ní ọdún 2024.
Ó fi kun pé lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan àti Yaba College of Technology tó wà ní Nàìjíríà nígbà tí òmìnira, tí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ti di 274, ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti di 183, tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni sì ti di 236 ní ìparí ọdún 2024.
Ètò ààbò
Ààrẹ ní àwọn ń tẹ̀síwájú láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sọ́ ààbò láti ri dajú pé ètò ààbò tó dájú wà ní Nàìjíríà àti láti ri pé ètò ọrọ̀ ajé rí ìrúgọ́gọ́ si.
Ó sọ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri pé ààbò tó dájú wà fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Ó ní wọ́n ń ṣẹ́gun tako àwọn agbéṣùmọ̀mí àtàwọn agbébọn tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ káàkiri Nàìjíríà pàápàá àwọn Boko Haram ní ìlà oòrùn àríwá, IPOB àti ESN ní ìlà oòrùn gúúsù.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ló ti ń padà sílé wọn látàrí bí àlááfíà ṣe ti padà sí ọ̀pọ̀ agbègbè táwọn agbéṣùmsmí ń dà láàmú.
Àwọn ọ̀dọ́
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́, ààrẹ ní àwọn ọ̀dọ́ ni ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà, tí wọ́n sì gbọdọ̀ máa tẹ̀síwájú láti máa ṣe àkánṣe lẹ́ka sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ẹ̀rọ, eré ìdárayá lójúnà àti mú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà.
Ó fi kun pé àwọn ṣe àgbékalẹ̀ NELFUND lát ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní 510,000 káàkiri gbogbo Nàìjíríà ti jẹ àǹfàní rẹ̀.
Ààrẹ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tó lé ní 228 ni wọ́n ti jẹ àǹfààní ètò ẹ̀yáwó tó tó N99.5bn láàárín ọdún kan ti wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí iye wọn jẹ́ 153,000 ni wọ́n ti jẹ àǹfààní ẹ̀yáwó ọgbọ̀n bílíọ̀nù náírà láti fi ra ọkọ̀, àwọn ohun èlò ilé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.