Lẹ́yìn tí BBC tú àṣírí àwọn tó ń fipá gba owó lọ́wọ́ awakọ̀ ní Ojodu-Abiodun, ìjọba ìbílẹ̀ Ifo fèsì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba ibilẹ Ifo, nipinlẹ Ogun, ti fesi si iwadii ileeṣẹ BBC Yoruba to tu aṣiri awọn ọmọ ita kan to n gba owo ode lorukọ rẹ.

Alaga ijọba ibilẹ naa, Idris Olalekan Kusimo, lo fi esi naa lede ninu atẹjade kan to ti sọ pe, awọn kọlọrọsi to da ọkọ ileeṣẹ wa duro, ti wọn si yọ nọmba idanimọ ọkọ wa kii ṣe oṣiṣẹ awọn.

Kusimo sọ pe "A fẹ ni sọ gbangba pe awọn eeyan naa kii ṣe oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifo, bẹẹ ni wọn ko ṣoju wa nibikibi.

Iriri awọn akọroyin BBC lọwọ awọn alọnilọwọ gba

Ẹnu iṣẹ ni awọn oṣiṣẹ BBC Yoruba n lọ ni ọsẹ bii meji sẹyin nipinlẹ Ogun, ki wọn o to o pade awọn kan to pe ara wọn ni oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa to da ọkọ wọn duro.

Bi wọn ṣe de agbegbe Ojodu si Akute, ni awọn gende ọkunrin meji kan da ọkọ duro, ti wọn si gbe igi di oju ọna.

Oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifo nipinlẹ Ogun ni wọn pe ara wọn. Bi wọn ṣe da ọkọ wa duro ni wọn beere fun iwe kan ti wọn lo n jẹ JTB.

Nnkan ti awọn eeyan yii to pe ara wọn ni oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifo, kọkọ ma n ṣe ni pe, wọn yoo gbe igi di ọna ibi ti ọkọ n gba kọja.

Ti wọn ba ti da ọkọ duro, wọn yoo beere iwe kan ti wọn n pe ni JTB. Awakọ ti ko ba ti ni iwe naa, kia, irinajo di ọfiisi wọn to wa ninu ile kan ni Ojodu-Abiodun.

Owo afi ipa gba kan, ẹgbẹrun mẹwaa, ni wọn o kọkọ gba lọwọ awakọ naa.

Lẹyin naa ni wọn yoo sọ pe ko san owo iwe ẹri JTB ọhun.

Nnkan iyalẹnu kan to wa lori ọrọ owo naa ni pe, ko si koko iye to jẹ - iye ti ẹni to wa ninu ọfiisi naa ba sọ pe o jẹ naa ni.

Fun awọn akọroyin BBC, ẹgbẹrun lọna aadọrin naira, 70,000, ni wọn kọkọ pe owo iwe ẹri JTB. Amọ, lẹyin ọpọlọpọ iduna-dura, ẹgbẹrun lọna marundinlaadọta, 45,000 ni awọn akọroyin naa san.

"A kọkọ yari pe a ko nii san owo naa nigba ti wọn sọ pe inu apo asunwọn ẹnikan, ti kii ṣe ti ijọba ni ka san owo naa si.

"Wọn ni ẹni naa ni alamojuto, aladani, ti ijọba yan lati ma ba a mojuto ọrọ iwe ẹri naa."

Igbesẹ awọn akọroyin BBC yii bi awọn to wa ni ọfiisi ti wọn ti n gba owo naa ninu, debi i pe, nigba ti awọn oṣiṣẹ wa gba lati san owo naa, wọn ni awọn ko gba a sinu apo asunwọn naa mọ.

Inu ṣọọbu ẹnikan to n ṣe POS ninu ọgba naa, ni wọn dari wọn si lati lọ ọ gba owo wa.

Lẹyin ti awọn akọroyin BBC ko owo le wọn lọwọ tan, ṣebi o yẹ ki wọn o kọ risiiti, iyẹn iwe to ṣafihan rẹ pe, wọn san "owo itanran ati owo iwe ẹri JTB".

Wọn kuku ko awọn iwe kan fun wa, amọ ofifo ni awọn iwe naa wa.

Ibeere nla ni pe, taa ni awọn eeyan to n da ọkọ duro, gbe igi dina, fi ipa gba owo sinu aka-n-ti ti kii ṣe ti ijọba ipinlẹ Ogun?

Ijọba ibilẹ wa ko ran wọn niṣẹ - Alaga ijọba ibilẹ Ifo

"Ijọba ibilẹ wa ko ran wọn niṣẹ, bẹẹ ni a ko gba owo kankan lọwọ wọn lori iṣẹ ti ko ba ofin mu ti wọn n ṣe ninu eyii ti wọn ti n fi ipa yọ nọmba idanimọ ọkọ awọn eeyan lati fi agidi gba owo lọwọ wọn."

Eyi ni nnkan ti alaga ijọba ibilẹ Ifo, Ọgbẹni Olalekan Kusimo, sọ lẹyin ti fidio BBC jade.

Bo tilẹ jẹ pe Kusimo sọ pe inu ọgba ijọba ibilẹ oun ni ọọfisi awọn kọlọrọsi naa wa, awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ Ifo ko mọ nnkankan nipa "iwa ọdaran" ti wọn n wu.

O fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii ni kikun lori awọn eeyan naa to n ba orukọ ijọba ibilẹ ọhun jẹ.

Alaga naa tun rọ gbogbo awọn ọlọkọ ti awọn kọlọrọsi naa ti fi ipa gba owo lọwọ wọn, to fi mọ BBC Yoruba, lati pese ẹri siwaju si lọna ati kin iwadii awọn lẹyin bo tilẹ jẹ a ti pese ẹri to dantọ ninu iroyin ti a fi lede ṣaaju.

O wa rọ araalu lati maa bun awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ naa gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba tun pade awọn eeyan naa to ni kii ṣe oṣiṣẹ awọn.

Lẹyin naa lo ni ijọba ibilẹ ọhun ko ni lọwọ ninu iwa ọdran kankan ati ohun ti yoo ba orukọ rẹ jẹ.

Atẹjade yii lo jade lẹyin ti BBC tu aṣiri awọn kan to n fi tipa tikuku ja tikẹẹti fun awọn ọlọkọ lagbegbe Ojodu-Abiodun, ni ijọba ibilẹ Ifo, nipinlẹ Ogun.

Lẹyin ti a gbe fidio iwadii wa jade ni ọpọ awọn ti awọn eeyan naa ti fi agidi gba owo lọwọ wọn bẹrẹ si n kin iwadii wa lẹyin ti wọn si n sọ iriri wọn lọdọ awọn kọlọrọsi ọhun.