Fídíò ìdúnù ẹbí kan tó jàjà rí ìyẹ̀fun oúnjẹ gbà di ìlúmọ̀ọ́ká lórí ayélujára

Fídíò ìdúnù ẹbí kan tó jàjà rí ìyẹ̀fun oúnjẹ gbà di ìlúmọ̀ọ́ká lórí ayélujára

Idile naa kun fun ayọ lẹ̀yin ti wọn jaja ri iyẹfun ounjẹ gba lẹyin ti gbogbo nnkan le koko ni Gaza, paapaajulọ ari ri ounjẹ jẹ.

Ko din ni ọgọrun un ajọ aṣeranwọ ti wọn ti n ṣekilọ pe ebi aparannu ti n gbilẹ kaakiri Gaza ti wọn si n na ika aleebu si orilẹede Israel pe o n bẹgidina pinpin ounjẹ nibẹ.

Amọṣa orilẹede Israel n sọ pe ẹgbẹrun kan o din aadọta ọkọ to ko nnkan amayedẹrun lo n duro bayii ninu Gaza fun awọn ajọ agbaye lati tẹwọ gba wọn.

Nibayii naa, awọn oluwọde ni Israel n gbe apo iyẹfun ti wọn si n rọ ijọba lati dẹkun iyan ati ogun ni Gaza.