Ǹjẹ́ àdéhùn jógun-ó-mí lè fòpin sí ogun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Donald Trump kede ni irọlẹ Ọjọ Aje pe Israeli ati Iran ti gba lati towọbọ adehun jogun-o-mi, to si tun sọ pe o le ja si alaafia pipẹ.
Eyi waye lẹyin ọjọ mejila ti Israeli kọlu Iran, igbẹsan Iran ati awọn ikọlu drone lori Israeli, ati jiju ado oloro si aaye iparun Iran lati ọwọ Amẹrika.
Iran sọ pe oun ti ṣetan lati da ikọlu rẹ duro ti Israeli ba da awọn ikọlu rẹ duro, ati pe ijọba Israeli sọ pe oun ti gba lati da ogun naa duro lẹyin ti wọn ti ṣe ohun ti wọn fẹ sẹ lori ikọlu si Iran.
Adehun jogun-o-mi wa laarin orilẹede mejeeji bayii, amọ ẹsun n jade pe Israeli ati Iran ti tapa si adehun naa.
Ireti wa pe alaafia jọba laarin orilẹede mejeeji ti adehun naa ba le fẹsẹ mulẹ.
Ki ni itumọ adehun jogun-o-mi?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bii ajọ UN ṣe sọ, ko si itumọ kan pato fun ọrọ jogun-o-mi, bo tilẹ jẹ pe, ọrọ wa lati ọdọ ileeṣẹ ologun, ti idakeji rẹ tumọ si pe ki wọn sina bolẹ.
O le tumọ si ohunkohun ti awọn ikọ ọmọ ogun mejeeji gba lati tumọ si ninu awọn idunadura wọn.
O sọ pe "idaduro awọn ija" duro lati jẹ adehun ti kii ṣe alaye lati da ija duro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun apẹẹrẹ, ogun abẹle kan ni Liberia wa si opin ni 1993 nigba ti Ijọba National Unity ṣe adehùn pẹlu Ẹgbẹ National Patriotic Front of Liberia and the United Liberation Movement of Liberia fun ijọba awarawa.
Awọn ẹgbẹ mejeeji gba lati dẹkun gbigbe awọn ohun ija wọle, lati ma ṣe paarọ tabi kọlu awọn ipo ologun, lati ma ru ija si siwaju sii.
N jẹ adehun Jogun-O-Mi le mu opin ba ogun tabi igba diẹ lo wa fun?
O le jẹ mejeeji, gẹgẹ bi ajọ United Nation ṣe sọ.
Nigba mii, awọn igun mejeeji ti wọn n bara wọn ja le fẹnuko fun adehun Jogun-O-Mi fun igba ranpẹ.
Eyi le jẹ lati dinku iwa-ipa tabi dinku idaamu omoniyan kan.
Nigba ti Israeli ati awọn ẹgbẹ ọmọ ogun ti o dari Hamas gba ifopin si ogun, eyi ti o waye laarin ọjọ kẹrindinlogun, Oṣu kọkanla ati ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun 2023, Hamas tu awọn ẹlẹwọn to le ni ọgọrun un silẹ lati gba awọn ẹlẹwọn wọn to jẹ 240.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Oṣu Karun un ọdun 2000, Ethiopia ati Eritrea fowo si adehun kan lati da rogbodiyan duro lati le ni anfani si adehun jogun-o-mi.
Eyi ti wọn fi ọwọ si ni oṣu Kejila, gẹgẹ bi apakan ti Adehun Algiers lo pari ogun wọn.
Ajọ UN ṣe ijiroro ọpọlọpọ jogun-o-mi lati fopin si ogun abẹle ni Lebanon – ni ọdun 1978, 1981 ati 1982.
Fun apẹẹrẹ, Adehun Good Friday Agreement ni ọdun 1998 ni Northern Ireland ṣe pẹlu IRA ati awọn ẹgbẹ oloootọ fẹnu ko lati fi awọn ohun ija silẹ.
Adehun naa tun ni awọn gbolohun ọrọ ti wọn pinnu lati ṣe igbelaruge alaafia ati isokan ni agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












