Ta ni Ruth Otabor, àbúrò Phyna tí ọkọ̀ iléeṣẹ́ Dangote ṣokùnfà ikú rẹ̀?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ Dangote Group ti fi ẹ̀dùn ọkàn hàn lórí ikú Ruth Otabor tí ọkọ̀ iléeṣẹ́ náà kọlù ní ìlú Auchi, ìpínlẹ̀ Edo ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn.

Ruth Otabor ló jẹ́ àbúrò Josephine Otabor tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Phyna tó jẹ́ ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò Big Brother Naija Season 7.

Ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 ni ẹbí Ruth fi àtẹ̀jáde kan látọwọ́ iléeṣẹ́ agbẹjọ́rò kan tí orúkọ ń jẹ́ Eko Solicitors & Advocates kéde ikú Ruth, tí wọ́n sì nǹkan bíi aago mẹ́fà ààbọ̀ òwúrọ̀ ló jáde láyé.

Àtẹ̀jáde náà tí Phyna fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ sọ pé inú ìbànújẹ́ àti ìpòruru ọkàn ni ẹbí náà wà báyìí, tí wọ́n sì nílò ààyè láti dárò Ruth.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn máa fi bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ léde láìpẹ́.

Kí ni iléeṣẹ́ Dangote sọ?

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ Dangote Group fi síta lọ́jọ́ Àìkú sọ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti gbé Ruth ló sí orílẹ̀ èdè India fún ètò ìwòsàn tó péye, tó sì jẹ́ pé àwọn ń retí káwọn dókítà tí wọ́n ń tọ́jú rẹ̀ fún àwọn ní àǹfààní láti máa gbe lọ kó tó di pé ó jáde láyé.

Iléeṣẹ́ Dangote ní ìbànújẹ́ ńlá ni ikú Ruth Otabor fún àwọn, tí wọ́n sì bá àwọn ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ Ruth kẹ́dùn lórí ikú rẹ̀.

"Láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ náà ti wáyé ni àwọn òṣìṣẹ́ wa, àti iléeṣẹ́ adójútòfò tí à ń bá ṣiṣẹ́ pọ̀ ti ń ṣùgbá rẹ̀, tí à ń ná owó ìlera àti àtìlẹyìn fáwọn ẹbí rẹ̀," iléeṣẹ́ náà kọ nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ìkànnì X wọn lọ́jọ́ Àìkú.

"A ti ṣe gbogbo ètò láti gbé e lọ sí India fún ìtọ́jú tó péye, tí à ń sì ń retí kí àwọn dókítà fún wọ́n í ìyọ̀nda láti gbé e lọ ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú yìí ló já sí pàbó."

Iléeṣẹ́ Dangote Group ní ètò ààbò, wíwà ní àlááfíà, àti níní ìmọ̀lára nípa èèyàn jẹ́ àwọn nǹkan tó jẹ́ iléeṣẹ́ àwọn lógún àti pé àwọn ní ìfàrajìn láti túnbọ̀ máa mú ètò ààbò ní ọ̀kúnkúndùn àti láti máa ṣe àtìlẹyìn fáwọn tó bá fara kásá nígbà tí ìjàmbá bá wáyé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára ni wọ́n ti ń ba Phyna àti gbogbo ẹbí Ruth Otabor kẹ́dùn lórí ikú ọmọbìnrin náà.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ èèyàn tún ń pè fún ìdájọ́ òdodo lórí ìjàmbá tó gbẹ̀mí ọmọbìnrin náà.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 ni ọkọ̀ ńlá tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ Dangote Group kọlu Ruth ní agbègbè ilé ẹ̀kọ́ Auchi Polytechnic ní ìpínlẹ̀ Edo.

Ìjàmbá náà mú kí Ruth wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run láti tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ abẹ láti gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan.

Èyí mu kí ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí ọṣẹ́ ńlá àti ìjàmbá tí àwọn ọkọ̀ ńlá iléeṣẹ́ Dangote máa ń fà lójú ọ̀nà.

Ọ̀pọ̀ ló sọ pé iléeṣẹ́ Dangote gbọdọ̀ dìde láti fi òpin sí gbogbo àwọn ìjàmbá náà tó máa ń dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò láìpẹ́ ọjọ́.

Lẹ́yìn ìjàmbá náà ni iléeṣẹ́ Dangote Group kéde pé àwọn máa san gbogbo owó àti àwọn nǹkan tí wọ́n bá nílò láti fi du ẹ̀mí Ruth.

Phyna tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ruth náà nínú àtẹ̀jáde kan lórí ayélujára sọ fún iléeṣẹ́ Dangote láti san owó bílíọ̀nù kan náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

Ta ni Ruth Otabor?

Ruth Otabor ló jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe Auchi Polytechnic.

Òun ni àbúrò Josephine Otabor tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Phyna tó jẹ́ ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò Big Brother Naija Season 7.

Ọjọ́ Kẹfà tí Ruth parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni ọkọ̀ iléeṣẹ́ Dangote Group ṣe ìkọlù si ọ̀kadà tó gùn tó sì ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run láti ìgbà náà.

Ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ ni Ruth jáde láyé látàrí ìjàmbá ọkọ̀ náà.