You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aráàlù fọnmú lórí Pásítọ̀ tó ń gbẹ̀bí, pèsè ‘omi ayẹta’ fọ́mọ ìjọ
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n waye lori pasitọ ijọ New Jerusalem Deliverance Ministry, Peter Michonza ni ijọba ibilẹ Okene ni ipinlẹ Kogi.
Ẹsun ti wọn fi kan pasitọ naa ni pe o n funra ara rẹ gbẹbi awọn alaboyun ninu ijọ rẹ lai gba aṣẹ ijọba.
Awọn to fi ẹsun kan an nipe awọn obinrin miran ti jẹ oku latari igbẹbi ti pasitọ naa n ṣe.
Okiki pasitọ naa lo kan kaakiri ayelujara lẹyin ti fidio ibi to ti n gbẹbi awọn obinrin jade soju opo ayelujara Facebook rẹ.
Bakan naa ni Pasitọ yii tun n fun awọn eniyan ni omi to pe ni ayẹta ‘’Bullet Proof water’’ fawọn ọmọ ijọ rẹ.
Pasitọ tun se ifẹhonuhan pe ki wọn fi R Kelly silẹ lọgba ẹwọn
Awọn eniyan tun bu ẹnu atẹ lu Pasitọ Peter Michonza nigba to ṣe ifẹhonu han nipinlẹ Kogi.
Ifẹhonuhan naa lo wa lati fi aidunnu rẹ han lori gbajugbaja olori R Kelly, ti wọn fi si sọgba ẹwọn lori ẹsun ṣiṣe aitọ pẹlu ọmọde.
''Orukọ mi ni Peteru to n ṣoju Baba rẹ ni ilẹ aye''
Awọn fidio to wa ni oju opo Facebook Pasitọ Peter Michonza safihan ibi to ti n gbẹbi, to tun n se ‘’iwosan’’ ti a ko lee fi idi rẹ mulẹ.
Amọ bi awọn kan ṣe n tako, ni awọn miran n gboriyin fun ni oju opo naa.
Bakan naa ni oju opo Facebook rẹ sapejuwe rẹ gẹ gẹ bi ‘’Peter, ọmọ to n ṣoju baba rẹ ni aye.’’
Iwadii ni iṣẹ orin kikọ ati fiimu ṣiṣeni pasitọ Peter Michonza n ṣe tẹlẹ, ki o to bẹrẹ ile ijọsin rẹ.
Inu bi mi nigba ti mo ri ohun ti pasitọ yii n ṣe - Aṣoju ijọba ipinlẹ Kogi
Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Kogi lori agbelarugẹ agbegbe, Suleiman Adinoyi sọ iriri rẹ nigba ti o de ile ijọsin naa.
O ni oun lọ sibẹ nigba ti mọlẹbi oun kan n rọbi ni ile ijọsin naa, ti wọn si fi to oun leti.
‘’Nigba ti mo de ibẹ , mi o le sọ boya pasitọ ni amọ o da mi loju pe kii ṣe dokita, o kan n fi ẹmi awọn alaboyun we ewu ni.’’
"Awọn ọmọ ijọ Pasitọ yii maa n doju bolẹ kii ni, baba ati olugbala si ni wọn n pe e"
Adinoyi tẹsiwaju pe "Bi mo ṣe de ibẹ ni mo beere ẹni to jẹ adari ni ṣọọṣi naa amọ wọn ko fẹ ko yọju si mi , igba ti mo da wahala silẹ nibẹ ni o to yọju’’
Bi o ṣe de ibẹ ni awọn eniyan doju bolẹ, ti wọn si n pe ni baba wọn ati olugbala wọn.
Mo beere lọwọ rẹ pe ṣe dokita ni abi pasitọ, to si dahun pe oun kii se dokita amọ ile Ọlọrun ni, ti oun si n ṣe ohun ti eniyan ko le ṣe.
Mo sọ fun pe mo wa gbe ibatan mi to wa nibẹ ni amọ o kọ jalẹ pe ọkọ ati iyawo ti buwọlu pe ki o wa ni ikawọ oun.
Nigba ti mo yari ni mo wọ ibi ti ibatan mi wa, nibi to ti n jẹ irora amọ o yari pe oun ko ni tẹle mi’’
Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lo gba lati tẹle mi, amọ nigba ti a de ile iwosan ni dokita ni ọmọ inu rẹ ti ku’’
Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lórí Pásítọ̀ tó ń ta omi ayẹta - Ìjọba ìbílẹ̀ Okene
Alaga ijọba ibilẹ Okene, Abdulrazaq Muhammad ti paṣẹ fun awọn eleto aabo lati ṣewadii ile ijọsin pasitọ Peter Michonza.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori Pasitọ naa ati gbogbo ohun to n ṣe ninu ile ijọsin rẹ.
Alaga naa dupẹ lọwọ awọn eniyan to pariwo sita nipa iṣe pasitọ naa.
O si fi da awọn eniyan loju pe gbogbo rẹ ni awọn yoo tu sita nigba ti iwadii ba pari.
Bakan naa ni wọn ti kesi Ajọ to n ri ọrọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN lati sabojuto ohun ti pasitọ naa n gbe ṣe ni ipinlẹ Kogi.