You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba Èkó fẹ́ẹ́ kó danfo àti korope kúrò nílẹ̀?
Latigba ti iroyin kan ti gbode pe ijọba ipinlẹ Eko fẹẹ fi ofin de awọn ọkọ danfo ati korope niluu Eko ni awọn eeyan ti n sọ ero ọkan wọn nipa igbesẹ naa.
Iroyin to n ja ran-in ni pe gbogbo ipinlẹ Eko ni wọn yoo ti ko awọn ọkọ yii kuro nilẹ lọjọ kin-in-ni oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii, bẹẹ lawọn kan n sọ pe agbegbe Lekki-Epe nikan ni.
Lati tan imọle si ọrọ yii, Oludamọran pataki fun Gomina Babajide Sanwo-Olu lori igbokegbodo ọkọ, Sola Giwa, ṣe awọn alaye kan loju opo X rẹ bayii pe:
‘’Ki eto irinna le rọrun fun gbogbo eeyan l’Ekoo ni ijọba ṣe bẹrẹ ilana Bus Reform Initiative (BRI).’’
‘’Gẹgẹ bi ilana tuntun tijọba ṣi fẹẹ wo bi yoo ṣe ri, wọn yoo pese awọn ọkọ mii ti yoo maa na Lekki-Epe.’’
Giwa sọ pe awọn danfo to ba ṣi duro daadaa ni ibamu pẹlu ofin awọn VIS to n yẹ mọto wo, yoo ṣi maa ṣiṣẹ diẹdiẹ.
Bẹẹ si ni awọn korope to ba ṣi daa naa yoo maa ṣiṣẹ loju ọna bii Obalende/CMS si Ajah, paapaa julọ, Ẹlẹkọ.
Kí ni yóò ṣẹlẹ sí dáńfó àti kórópe?
Oludamọran ijọba Eko lori ọrọ ọkọ wiwọ ṣalaye pe,
‘’Danfo ati Korope yoo ni lati lọ fun ayẹwo ti yoo sọ boya wọn ṣi le rin loju ọna yii, awọn awakọ yoo si gba idanilẹkọọ to peye nileewe ẹkọ nipa mọto wiwa to jẹ ti ijọba.
‘’ A o pin ọna ti kaluku yoo maa na fun wọn, a o si maa wo bi wọn ṣe n tẹle ilana ọhun si.
‘’Idẹrun awọn ero ọkọ jẹ wa logun gidi, fun idi eyi, ijọba yoo ṣeto bi wọn ṣe le maa ra tikẹẹti ọkọ wiwọ lori ayelujara.
‘’Amojuto gidi yoo wa lori awọn ti wọn maa n gbe ero nibi ti ko tọ, ati awọn ibudokọ ti ko tọna labẹ ofin.’’
Ipade awọn tọrọ kan waye lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2024 yii, awọn olori ẹgbẹ onimọto, dẹrẹba, awọn oṣiṣẹ lati ẹka ijọba to n ri si igbokegbodo ọkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn peju sibẹ.
Nibi ipade naa ni wọn ti yanju gbogbo ohun to ruju bi Sola Giwa ṣe wi.
O ni igbesẹ yii ti mu kawọn ọlọkọ forukọ silẹ lẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si irinna.
Titi dasiko ti a pari iroyin yii ṣaa ni awọn eeyan ṣi n sọ pe alaye to role apa kan ni Giwa ṣe yii, wọn ni bijọba ba fi ko awọn danfo ati korope kuro nilẹ, aa jẹ pe inira ni wọn fẹẹ ko ara Eko si.