You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iṣẹ́ ọṣẹ tí mo padà kọ́, ni kò jẹ́ kí n di alágbe lẹ́yìn tí ojú mi fọ́
Yoruba ni, ko sẹ ni to mọla, nitori pe Ọlọrun nikan lo mọ ohun gbogbo.
Wọn o bi Ọgbẹni Abudulhadi Zakariyah ni afọju, koda, o ti dagba, o ti di baale ki oju rẹ to o fọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo, ori fifọ lo kọkọ bẹrẹ, to si lọ si ileewosan.
Ipadabọ ori fifọ naa lẹyin ayẹwo awọn dokita ni pe oju rẹ fọ nitori aisan oju ti wọn n pe ni, Glaucoma.
"Wọn o bi mi mọ iṣẹlẹ yii, mo ni anfaani bi wọn ṣe n bi awọn ọmọ ki wọn barika, wọn bi emi naa, mo dẹ ṣe kekere, mo ni anfaani lati kọṣẹ aṣọ riran."
"Ni igba to di ọjọ kan, iyẹn lọdun 2006, ori n fọ mi wẹrẹ wẹrẹ, mo ra ogun, mo lo, mo ri wi pe ko mu, mo lọ si ile iwosan, lẹyin naa ni awọn dokita n sọfun mi wi pe aarun Glacoma ni."
Ọgbẹni Zakariyah ṣalaye pe, nigba ti ipenija oju de si oun, o dabi n pe aye ti dopin.
O ni, oju kan ti oun ba joko si bayii, ohun naa ni oun yoo joko "afi ti mo ba mu nnkankan tabi ṣe nnkankan ni maa kuro nibẹ. Fun aimọye ọdun ni mo fi duro ni ile."
Eto kan to gbọ lori rẹdio lo yii aye rẹ pada.
"Ọjọ kan n bẹ ti mo ṣe alabapade eto kan, eto lori redio ni, nibi ti wọn ti sọ lọjọ naa pe to ba ni ipenija bayii, aiye o dopin o, o si le tẹsiwaju.
Ti ọjọ ori rẹ ba ti kọja ẹni to le kawe si, awọn iṣẹ ọwọ kan nbẹ to le kọ. Koda wọn le kọ ẹ bo ṣe le rin lati ibi kan si ibi kan, mo ni maa lọ, mo gba fọọmu, igba temi naa debẹ, mo turaka, mo ri pe aye o pin sibẹ bi a ṣe kọ iṣẹ ọṣẹ yii niyẹn."
"Ipenija to ga julọ ti a n kọju ohun ni ipenija awujọ, tẹ ba duro ni opopona, pe ẹ fẹ da mọtọ duro, tabi tẹ gbọ ohun lẹgbẹ yin, tẹ ba pe wọn, wọn maa yẹra, ẹlomi a dahun, ẹlomi a fi owo gun yin lọwọ nitori wọn maa ro pe bi o ṣe mu ẹ; tawọn ba ti fọwọkan ẹ, o maa ran awọn naa tabi boya ẹṣẹ kan ni eeyan ṣẹ Ọlọrun t'eeyan fi wa ninu iṣoro yii."
Arakunrin naa sọ pe ti ko ba n ṣe ọla iṣẹ ọsẹ ṣiṣe ti oun lọ ọ kọ ni, oun naa i ba i maa tọrọ jẹ ni ẹgbẹ titi.
"Imọran mi fun awọn to jẹ akanda, akọkọ tẹ ba ti ri eeyan to ni ipenija bayii, tẹ ri pe o n kajọ, ẹ pe jade, ẹ maa jẹ ko joko sile o, ko jokoo ko s'anfaani fun, ki wọn si maa mu kaakiri tọrọ owo, ko s'anfaani kan fun.
Mi o ro pe ọjọ kan wa ti mi o maa n ronu nipa iṣẹ mi, paapaa julọ ijọ ti mo ba fẹ gbe aṣọ fun tailor kan, to ba bu owo fun mi, ori mi a tana wi pe kini eyi to n ṣe yii, o maa wu mi pe ki n kan ji nijọ kan, ki oju mi kan laa niiṣe ni maa tẹsiwaju pẹlu iṣẹ mi, ojojumọ mi mo maa n ro.
Ki ni dokita sọ nipa aisan Glaucoma?
Dokita Taoheed Abdullahi sọ pe ti eeyan ba ni aisan Glaucoma, ẹgbẹẹgbẹ ni iriran ti maa bẹrẹ si n bujẹ diẹ diẹ.
O ni diẹdiẹ ni oju naa yoo ma a pade titi yoo fi bajẹ tan.
"Igba yẹni ni iru eeyan bẹẹ yoo kiyesi pe oju oun n ṣe kurukuru, o dabi n pe ojo fẹ rọ, abi iri n ṣẹ, oriṣiriṣi iṣoro bayii ni awọn eeyan maa ni, igba yẹn ni wọn ṣẹ maa wa si Ile iwosan, igba yẹn si ni, aisan yẹn ti ba oju jẹ jinaa."
Dokita Abdullahi ṣalaye pe itọju wa fun aisan Glaucoma, ti ko ba ti i fọ oju tan yanyan, ṣugbọn t'eeyan ba pa Glaucoma yii ti, tabi ti eyaan o lọ ṣe ayẹwo ko fi le mọ pe oun ni i , iyẹn lo maa n faa, ti oju ṣe maa n fọ.
Ki lo n fa glaucoma?
Dokita Abdullahi tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, lara awọn nnkan to maa n ṣe okunfa rẹ ni pe, ti bi oju ṣe n ṣiṣẹ si, eyi ti wọn n pe ni eye pressure, ba di pe o tayọ ju oṣuwọn to yẹ ko wọn.
Idi keji ni pe ti t'eeyan ba ti ni ẹnikan to ni glaucoma ninu mọlẹbi, boya baba tabi iya, o si le jẹ ọmọ iya eeyan , iyẹn naa le ṣokunfa k'eeyan tun ni.
Ẹka ijọba apaapọ fun eto ilera sọ pe aisan Glaucoma ni iwọn 16.7% ninu oṣuwọn afọju lorilẹede Naijiria.