You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó ti di èèwọ̀ f'áwọn obìnrin láti máa kẹ́kọ̀ọ́ ní fásitì ní Afganistan láti àkókò yíì lọ- Taliban kéde
Ijọba Taliban ni Afganistan ti sọ pe o ti di eewọ bayii fun awọn obinrin lati kẹkọọ ni fasiti kaakiri orilẹ-ede naa.
Minisita to n ri si eto ẹkọ ilẹ naa lo fi ikede ọhun sita.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ tuntun naa yoo mulẹ titi ti awọn yoo fi yi ipinnu wọn pada, amọ awọn ko tii le sọ igba ti yoo jẹ.
Ṣaaju ikede tuntun yii ni Taliban ti kọkọ sọ pe awọn obinrin gbọdọ yago fun ile ẹkọ girama.
Ọkan lara awọn akẹkọọ ni fasiti Kabul sọ fun BBC pe ṣe ni oun n wa ẹkun mu lati igba ti ikede naa ti jade.
Loṣu mẹta sẹyin ni ẹgbẹgbẹrun awọn ọdọbinrin kọ idanwo aṣewọle si awọn fasiti kaakiri orilẹ-ede naa.
Lẹyin naa ni ijọba Taliban sọ pe awọn obinrin ko le kẹkọ nipa awọn ẹkọ imọ bii eto iṣiro, eto agbẹ, imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ.
Lẹyin ti Taliban gbajọba Afganistan lọdun to kọja ni awọn fasiti ṣe ipinya bi awọn akunrin atawọn yoo ṣe maa joko ati bi wọn yoo ṣe maa kọ wọn ni kilaasi.
To n tumọ si pe olukọ obinirin nikan lo lẹtọ lati maa kọ awọn obinrin nigba ti awọn olukọ ọkunrin yoo maa kọ awọn ọkunrin nikan.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ tuntun naa, ọkan lara awọn akẹkọbinrin naa sọ pe igbagbọ oun ni pe Taliban n bẹru awọn obinrin ati irufẹ agbara ti wọn ni lo jẹ ki wọn gbe irufẹ ofin bẹẹ sita.
O ni “Taliban ti ja afara to so emi ati ọjọ iwaju mi pọ.”
Ẹwẹ, igbakeji aṣoju ijọba ilẹ Amẹrika si ajọ United Nations, Robert Wood ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Taliban ọhun.