You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò sí ohun tí yóò yẹ ìdìbò gbogbogbò tó ń bọ̀ lọ́nà – Ìjọba àpapọ̀
Ijọba apapọ Naijiria ti ni irọ ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri pe Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ gbe ijọba fidihẹ kalẹ lẹyin saa rẹ
Agbẹnusọ Aarẹ, Garba Shehu lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjde kan, nibi to ti sọ pe ijọba fidihẹ ko si ninu erongba Buhari.
O ni “Ọrọ ijọba fidihẹ kii ṣe ara rẹ rara.”
“Awọn to n gbe iroyin naa kiri ko le ri ere kankan nidi rẹ ju pe ki wọn da ipaya sọkan awọn araalu lọ, ki wọn si kọ ẹyin araalu si ijọba.”
“Igbesẹ naa jẹ ohun ti awọn eeyan kan ti wọn n bẹru pe wọn le lulẹ ninu eto idbo to ku ọsẹ kan bayii n gbe.”
Bo tilẹ jẹ pe o gba pe iṣoro wa ninu ilana to rọ mọ owo naira tuntun, Shehu rọ awọn araalu lati ma paya rara.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ohun ti awọn araalu n dojukọ n kọ Aarẹ lominu, o si ti n wa ọna abayọ si iṣoro ọhun, lara eyii to mu ko ba awọn eeyan sọrọ laarọ Ọjọbọ.
O fi kun pe lai si aniani, Bola Ahmed Tinubu ni Aarẹ Buhari n fẹ ko gbajọba lẹyin oun.
Atẹjade Shehu yii lo n jade lẹyin ọrọ ti gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, sọ pe gomina CBN atawọn eeyan kan to sun mọ Aarẹ fẹ mọọmọ fi aye ni awọn araalu lara.
El-Rufai sọ fun awọn eeyan ṣaaju pe awọn kan wa ti ko fẹ ki akitiyan ijọba so eso rere lọna ati ri pe idibo gbogbogbo to n bọ ko waye.
Gẹgẹ bii ohun ti El-Rufai sọ, afojusun awọn eeyan ọhun ni ki ologun gbajọba latari awọn inira ti awọn ọmọ Naijiria n dojukọ lasiko yii.