Wo àtúpalẹ̀ orílẹ̀èdè Togo lábẹ́ ìjọba ìdílé Gnassingbé

Faure Gnassingbé was sworn in to office in February 2005 at the presidential palace in Lomé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Beverly Ochieng & Tom Santorelli
    • Role, BBC Monitoring, Nairobi and BBC News, London

Kaakiri agbaye lawọn idile kan ti maa n wa ni ijọba fun ọpọ ọdun.

Bẹrẹ lati idile Bush nilẹ Amẹrika, si ti Kim ni North Korea, idile Bhutto ni Pakistan, Trudeau ni Canada, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni Togo, to wa ni iwọ oorun ilẹ Afrika, idile Gnassingbé lo ti n tukọ orilẹede naa fun nnkan bii ọgọta ọdun.

Ọmọ idile naa ni Faure Gnassingbé to gori alefa lati ọdun 2005 titi di akoko yii.

Ni bayii ti Faure Gnassingbé n gbe igbese lati ṣatunse si ofin ti yoo mu ko tun tẹsiwaju lori oye, araalu ti n yari.

Idile Gnassingbé

Lọdun 1967, ọmọ oṣu mẹsan an pere ni Aarẹ to wa lori alefa bayii wa nigba ti baba rẹ Gnassingbé Eyadéma ditẹ gbajọba.

Lẹyin ti Gnassingbé Eyadéma ku lọdun 2005, ọmọ rẹ Faure Gnassingbé gori alefa, o si ti sa ipa rẹ ki awọn mii ma baa gba ijọba lọwọ oun naa.

Ni bayii ti ile aṣofin ti ṣatunṣe si ofin ilẹ naa, o ṣeeṣe ki Faure naa wa lori oye titi di ọdun 2031.

Togolese opposition supporters during a protest in Lomé in September 2017

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Atunṣe ofin

Ṣiṣe atunṣe si ofin orilẹede Togo ni ọna alumọkọrọyi ti idile naa n lo lati joko sori aga Aarẹ.

Lọdun 2022, Aarẹ Eyadéma ṣatunṣe si ofin ilẹ naa to sọ pe saa meji pere ni Aarẹ le lo lori oye nipa ṣiṣe afikun si.

Nigba to gori alefa lọdun 2005, Faure Gnassingbé janfani atunṣe yii.

Lọdun 2017 ati 2018 to kọ lati gbe agbara silẹ, awọn ọdọ fẹhonuhan, bo tilẹ jẹ pe o gbiyanju lati tu wọn ninu, wọn yari kanlẹ.

Latari pe ifẹhonuhan naa tẹsiwaju, ijọba bẹgi dina oju opo ayelujara nitori ifẹhonuhan to n waye nibẹ pẹlu ami #TogoDebout.

Igbesẹ naa mu ki ile ẹjọ ẹkun iwọ oorun Afrika paṣẹ ko san owo itanran $3,400.

Lẹyinorẹyin, wọn dibo lọdun 2020, Faure si wọle fun saa kẹrin lẹyin to ni ida 70% ibo ti wọn di nilẹ ọhun.

Togolese President Faure Gnassingbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ buwọlu yii sọ?

Labẹ ofin yii, awọn ọmọ ile aṣofin ni yoo maa yan Aarẹ dipo araalu fun saa kan ti yoo jẹ ọdun mẹfa.

Wọn yoo tun ni ipo olootu ijọba ti yoo lagbara gẹgẹ bii Aarẹ.

Ẹgbẹ alatako mẹta; Alliance of Democracies for Integral Development (ADDI), Democratic Forces for the Republic (FDR) ati National Alliance for Change (ANC) to fi mọ ijọ Katoliiki ti sọ pe atunṣe ofin naa ko tẹ awọn lọrun.

Togo’s president poses with leaders of Ivory Coast, Niger, Chad, Burkina Faso, Senegal and Nigeria at an ECOWAS summit in September 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images