Ta a ni VDM áti Mr Jollof tí wọn fi eyín àti ẹ̀ṣẹ́ bára wọn jà nínú ọkọ̀ bàálù?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awuyewuye si n lori lori ija to bẹ silẹ ninu ọkọ baalu laarin Martins Vincent Otse ti ọpọ mọ si Very Dark Man ati Freedom Freedom Atsepoyi ti inagijẹ rẹ n jẹ Mr Jollof.

Fidio kan to lu ori ayelujara pa ṣafihan bawọn ọkunrin mejeeji ṣe lu ara wọn ti ẹnikan ninu wọn si ge ẹnikeji jẹ ninu ọkọ baalu United Nigeria lowurọ ana ọjọ Aje ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kọkanla yii ni papakọ ofurufu ilu Asaba nipnlẹ Delta.

Ohun ti a gbọ ni pe ajọ NCAA to n ri si irinajo ọkọ ofurufu ni Naijiria ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Lẹyin ti aawọ naa bẹrẹ laaarin awọn mejeeji lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ko awọn mejeeji lọ fawọn agbofinro.

Ta a ni Very Dark Man to ja ninu ọkọ baalu pẹlu Mr Jollof?

A bi Martins Vincent Otse tawọn eeyan mọ si Very Dark Man lọjo kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 1994 niluu Kaduna.

Bo tilẹ jẹ pe ilu Agenebode nipinlẹ Edo lawọn obi rẹ ti wa, ilu Kaduna ni Very Dark Man ti lo igba ewe rẹ.

Very Dark Man jẹ alẹnulọrọ lori itakun ayelura, ajafẹtọọ ọmọniyan ati ẹlẹyinju aanu si ni i ṣe.

Ọgbẹni Otse jẹ ẹnikan to maa n saba ṣe nkan to maa n jẹ kawọn sọrọ nipa rẹ loorekoore.

Very Dark Man maa n sọrọ tako iwa ajẹbanu, iwa ọdaran ati eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Ni gbogbo igba lo maa n beere fun idajọ ododo lawujọ.

Lọdun 2022 ni Very Dark Man bẹrẹ iṣẹ ajafẹtọọ to n ṣe lori itakun ayelujara.

O kọkọ bẹrẹ nipa biba awọn alẹnulọrọ lawujọ ṣe wọle wọde, lati ibẹ si ni ọpọ eeyan ti mọ ọn.

Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni pin oniruuru fidio tawọn eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara.

Okiki VDM ti kan kaakiri ko too di ọdun 2023, lọdun 2023 yii kan naa ni gbajumọ akọrin takasufee Davido di ọrẹ rẹ lori Instagram ti o si fi fontẹ lu nnkan to n ṣe.

Ọdun 2024 to tẹle e ni ileeṣẹ tẹfisan Sliverbird kede VDM gẹgẹ bii ọkan lara awọn oludije fun ami ẹyẹ alẹnulọrọ julọ lori ayelujara.

Ta ni Mr Jollof toun ati Very Dark Man jọ fa aawọ ninu ọkọ baalu?

Ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ ọdun 1987 ni wọn bi Freedom Okpetoritse Atsepoyi tawọn eeyan mọ si Mr Jollof nipinlẹ Delta.

Ilumọọka adẹrin-inpoṣonu ni Mr Jollof, bakan naa lo tun maa n ṣe sikiiti lori ayelujara.

Ṣaaju ni ede-ai-yede ti wa laaarin Mr Jollof ati VDM, eyi to jẹ ki iyawo Mr Jollof gbe VDM lọ ile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Esinjemiyotan Atsepoyi to jẹ iyawo Mr Jollof si rọ ile ẹjọ lati paṣẹ pe ki VDM san N500,000,000 gẹgẹ bii owo faini.

Iyawo Mr Jollof sọ pe VDM fẹsun kan oun pe oun n ni ibalopọ pẹlu awọn ọmọ ''Yahoo'' atawọn oloṣelu lati jẹ ki ijọba ipinlẹ Delta fun ọkọ oun nipo oludamọran agba si gomina ipinlẹ naa.

Mr Jollof si ti fun VDM ni oṣu kan lati yọju sile ẹjọ, bi bẹẹ kọọ, yoo kan idin ninu iyọ.

Ọrọ yii ti di nnkan tawọn eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara.

Ilu Warri nipinlẹ Delta ni wọn bi Mr Jollof si, ibẹ naa lo si dagba si bakan naa.

Kí ló fà á tí VDM àti Mr Jollof fi yọ ẹ̀ṣẹ́ sí ara wọn nínú ọkọ̀ bàálù?

Ileeṣẹ baalu United Nigeria Airlines ti fidi ija to waye ninu ọkọ baaluu laarin gbajugbaja alẹnulọrọ ori ayelujara, Matins Otse, ẹni ti ọpọ mọ si Very Dark Man (VDM) ati adẹrinpoṣonu, Freedom Atsepoyi, ti ọpọ mọ si Mr Jollof lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kọkanla yii mulẹ.

Eyi waye lẹyin ti fọnran kan lu sita sori ayelujara eyi to si ṣafihan bi ija ṣe bẹ silẹ laarin awọn mejeeji.

Agbẹnusọ ileeṣẹ baaluu naa, Chibuike Uloka, ninu atẹjade to gbe sita ṣalaye pe rogbodiyan naa bẹ silẹ lasiko ti baalu UN0523 fẹ gbera ni paapa ofurufu Asaba nipinlẹ Delta lowurọ Ọjọ Aje.

O ni lati ri pe aabo wa fun awọn ẹrọ ọkọ baaluu, awọn alaṣẹ yọ awọn meji to n ja naa kuro ninu baaluu, wọn si fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.

"Lati le tẹle ofin agbaye nipa aabo ọkọ ofurufu, awọn oṣiṣẹ wa yara pẹtu si rogbodiyan ti ṣẹlẹ ninu ọkọ baalu.

Wọn yọ awọn arinrinajo meji to n ja naa lati le pese aabo fun awọn arinrinajo yooku."

Uloka jẹ ko di mimọ pe awọn arinrinajo meji to n ja ọhun si wa ni ọdọ awọn agbofinro nigba ti ọkọ baaluu ti wọn ja ninu rẹ gbera kuro ni papakọ ofurufu Asaba.

Ohun pato to fa ija laaarin VDM ati Mr Jollof ni a ko le fidi rẹ mulẹ ṣugbọn ileeṣẹ ijọba to n ri si irinajo ọkọ ofuurufi, NCAA ni iwadii ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Fidio to lu sita lori ayelujara ṣafihan bi awọn ọkunrin mejeeji ṣe yọwọ ẹsẹ si ara wọn ninu ọkọ baaluu.

Awọn n gbọ bii VDM ṣafihan bi o VDM ṣe sun mọ Mr Jollof ṣaaju ki ija to bẹrẹ laaarin wọn.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oṣu diẹ ti NCAA fofin de gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Ayinde K1 De Ultimate pe ko ni lanfaani lati wọ ọkọ baaluu ni Naijiria fun oṣu mẹfa.

Ṣugbọn ajọ NCAA pada yi ohun pada, ti wọn si sọ K1 di aṣoju wọn.

Bakan naa ninu oṣu kẹjọ, NCAA fofin de arabinrin kan, Comfort Emmanson, to ṣe ikọlu sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air.

Comfort dero ọgba ẹwọn Kirikiri niluu Eko, amọ, wọn tun pada fi i silẹ lẹyin iwadii.