You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo iye ìgbà tí Portable ti ṣe nǹkan tó mú ọ̀pọ̀ èèyàn pariwo rẹ̀ lórí ayélujára
Gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Portable lo ma tun di ọrọ ti gbogbo aye n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara.
Portable ni ọpọ eeyan ti bu ẹnu ẹtẹ lu fun bi o ṣe di igbaju ru pasitọ kan to wa se iwaasu ni ile ọti rẹ niluu Sango Ota laipé yii.
Fọnran iṣẹlẹ naa lo lọ kaakiri lori ayelujara ninu eyi ti Portable si ti sọrọ nipa iṣẹlẹ naa.
Ninu fọnran ọhun, Portable n bi pasitọ naa leere pe ki lo n da awọn onibara rẹ laamu fun ni owurọ ọjọ Aje, ko to di pe o di igbaju lu u.
Portable sọ ninu fọnran naa wi pe “bayii ni wọn se n ba okowo jẹ fun eeyan, laarọ ọjọ Aje, o n ba okowo mi jẹ.
Mo ti gba adura fun ara mi ki n to kuro ni ile.”
Awọn ọrọ Portable ree ko to di pe o ni ki olusọ aguntan naakuro ni ayika rẹ.
Wọnyii ni iye igba ti ọrọ Portable ti di ariyanjiyan lori ayelujara.
Awọn Ẹgbọn adugbo lu Portable
Ni oṣu to kọja ni Portable kigbe sita lori ikanni ayelujara lati fi ẹsun kan awọn kan to pe ni ‘Ẹgbọn Adugbo’, to sọ pe wọn n dunkooko mọ oun.
Portable lori Instagram jẹ ko di mimọ pe awọn ‘Ẹgbọn Adugbo’ naa yabo oun ati awọn ọmọ ẹyin oun, ti wọn si lu awọn nilukulu.
Ninu fọnran ti ọdọmọkunrin ti wọn tun n pe ni Idaamu Adugbo naa gbe sita, o sọ pe ibi toun ti lọ kọrin lagbegbe Iju-Ishaga nipinlẹ Eko ni awọn eeyan naa ti wa lati da ibẹ ru.
O ni ọrẹ oun kan to n ta mọto loun lọ ba ṣe ayẹyẹ, toun si tun kọrin nibẹ pẹlu, ko to di pe wọn kọlu awọn.
Portable sun sinu Posi
Portable Ọmọ Olalomi tun ti gbe ara mi jade lẹyin to wọle si gbọngan ere ninu posi ni ile orin Fela niluu Eko.
Ohun iyalẹnu ati ifoya lo bade nigba ti awọn ọkunrin mẹrin kan gbe posi wọle si gbọngan naa, ti Portable si jade lati ninu posi ọhun.
Ninu fidio fọnran kan to gba ori ayelujara kan, Portable lo gbe ara rẹ sinu posi, ti awọn ọkunrin mẹrin si gbe posi ọhun wa si gbọngan ti yoo ti ṣe ere fun awọn ololufẹ rẹ.
Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti Portable yoo ṣe afihan ifẹ to ni si sisun ninu posi.
Portable sọrọ lori iyawo Alaafin
Portable tu kẹkẹ ọrọ sita lori ibasepọ rẹ pẹlu Olori Alaafin tẹlẹ, Damilola, aya alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, to ti waja
Portable ṣalaye ọrọ lasiko to fi n kopa lori eto kan lori ayelujara. O ni oun ko ba ti ni ohunkohun pẹlu iyawo Oba to ba jẹ pe Alaafin si wa laye ni.
O sọ ọrọ yii lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu Honest Bunch, to si jẹ ko di mimọ pe lẹyin Ọba, Ọba tun ni.
"Alatilẹyin mi lati ọjọ pipẹ ni, sugbọn nigba to ya, mo gbọ pe Ọba ti ku, lẹyin Ọba, Ọba tun ni.
"Ka ni Ọba si wa, ẹ ko ni ri emi ati rẹ papọ nitori n ko ki tẹle Iyawo oni iyawo kiri."
Ọlọpaa ati Portable
Lọdun to kọja, Ọwọ ọlọpaa tẹ Portable lẹyin ti wọn kede pe wọn fun un ni wakati mejilelaadọrin lati wa jọwọ ara rẹ ni agọ ọlọpaa fun ẹsun iwa ipa.
Ọpọlọpọ igba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fẹ mu gbajugbaja olori takasufe Portable, to si jẹ pe o ma n fẹ kọju oro si wọn ni.
Nigba akọkọ ti ọlọpaa fẹ mu Portable tori bo se fiya jẹ ọmọsẹ rẹ kan, se ni akọrin takansufe naa n pariwo le awọn ọlọpaa naa lori.
"Ọbọ ni mi, inu ọgba ẹranko ni mo n gbe" ni ariwo ti Portable mu bọ ẹnu.
Ko pẹ ni wọn tun mu tori pe ko san owo mọto to ra tan, se ni Were Olorin naa fo ògiri, to si fẹ sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ.
Ko si jẹ ohun iyalẹnu pe ọpọ awọn eeyan lo ma n fẹ salọ nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ba fẹ mu wọn pe wọn furasi pe wọn lọwọ ninu iwa ọdaran.