You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa ìlú Osi ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ti ń pèsè gaàrí tó dáa jù ní ilẹ̀ Yorùbá
Ìlú Osi, ní ìjọba Ekiti, ìpínlẹ̀ Kwara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí wọ́n tẹ̀dó lẹ́yìn tí àwọn Babańlá wọn kúrò ní ìlú Ilé-Ifẹ̀ tí Yorùbá gbà pé ó jẹ́ orírun wọn.
Ní ilẹ̀ Yorùbá, lẹ́yìn Gaárí ìjẹbu ati Ẹgba, ìlú Osi ló tún gbajúmọ̀ fún pípèsè gáàrí tó dára gidi.
Èdè Èkìtì ni wọ́n ń sọ ní ìlú Osi nítorí wọ́n súnmọ́ ara wọn púpọ̀.
Ọba onípò kìíní ni ọba ìlú Osi tó sì alága fún àwọn lọ́balọ́ba ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti ní ìpínlẹ̀ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú BBC News Yorùbá, Olosi ti ìlú Osi, Ọba Saliu Abdulkareem Adasofegbe ní ìtàn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ilé Ifẹ̀ ni orírun àwọn ti bẹ̀rẹ̀.
A gbọ́dọ̀ mú ètò ààbò ní òkúnkúndùn - Ọba Adasofegbe
Ọba Adasofegbe ní láti ìlú Ilé Ifẹ̀ ni àwọn babańlá àwọn ti ṣe ìrìnàjò kúrò tí wọ́n sì wá tẹ̀dó sí ibi tí àwọn mọ̀ ní ìlú Osi lónìí.
Ọba alayé náà ni pe gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní òde òní kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹrẹ nítorí láti ìgbà ìwáṣẹ̀ náà ni àwọn kan ti máa ń hu ìwà ìpátá.
Ó ní ìwà ìjínigbé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọde òní, ó kàn jẹ́ pé ìhà tí àwọn èèyàn kọ si ló yàtọ̀ lásìkò yìí.
Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú àwọn babańlá àwọn kọ́ odi yí gbogbo ìlú Osi ká nígbà náà láti fi pèsè ààbò tó yẹ fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn Osi.
Ó ní ó pọn dandan fún gbogbo ìlú kọ̀ọ̀kan láti mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti pèsè ààbò tó péye fún ará ìlú nítorí ètò ààbò lóde òní ń fẹ́ àmójútó tó péye.
“A kọ́ odi yí gbogbo ìlú Osi, tó ní géètì bíi mẹ́rin, tí a yan àwọn èèyàn tó ń ṣọ àwọn géètì náà síbẹ̀.”
Kini Kabiesi tun sọ?
Kabiesi Olosi sọ pe: “Ẹni tó bá fẹ́ wọlé, wọ́n á mọ ẹni tó jẹ́, a ní láti tọná ojú wa sílẹ̀ dáadáa nítorí ọmọdé nìkan kọ́ ni wọ́n ń jígbé, kódà, wọ́n ń jí ọba gbé.”
Olosi ní àwọn ní àwọn oríṣìí ẹgbẹ́ tó dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ ààbò èyí tó ń rí sí ètò ààbò ìlú náà lóde òní.
“A ní àwọn oríṣìí ẹgbẹ́, ẹgbẹ́ ìkòta ni bíi ọlọ́pàá ti wa, àwọn ikan ni bíi ọmọ ogun, tí wọ́n ń ṣọ àwọn ẹnubodè ìlú kọ̀ọ̀kan.”
“Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí a ní yìí jẹ́ kí ó nira fún àwọn aláburú láti ṣàadédé wọ inú ìlú Osi, ẹni tó bá ní ẹ̀mí aburú ni wọ́n máa ń tètè mọ̀ ní kíákíá.”
“Ó yẹ ká tọná ojú lẹ̀, ká ri pé àwọn èèyàn burúkú kò n ráyè wọ àárín ìlú.”
Ọba Adasofegbe tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun ìdàgbàsókè tó ń fẹ́ nínú ìlú Osi ki igbayegbadun awọn eniyan Osi le tubọ fini lọkan balẹ sii