'Àwọn ọkùnrin gan mọ̀ pé àwọn nílò àwa obìnrin nínú òṣèlú, ìdí tí èmi fi wọ òṣèlú ni pé...'

'Àwọn ọkùnrin gan mọ̀ pé àwọn nílò àwa obìnrin nínú òṣèlú, ìdí tí èmi fi wọ òṣèlú ni pé...'

Olùdíje sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun, Funlola Akinrinde ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ nínú òṣèlú láti ìgbà tó ti wà ní kékeré.

Ó ní láti ìgbà ayé AD ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe òṣèlú tí àwọn ènìyàn sì mọ òun, tí òun sì tún jẹ́ éni tó ń tẹ̀lé Bola Ahmed Tinubu.

“Nítorí ọmọ bíbí àti ìgbéyàwó ni mo ṣe dáwọ́ òṣèlú dúró díẹ̀ láti mójútó ìgbéyàwó mi àmọ òun ń ṣe gbogbo ohun tó tọ́ lábẹ́nú láti máa dá sí òṣèlú.

Ó ní kí àwọn obìnrin máa jáde tó láti díje dupò òṣèlú, nítorí náà, ó ní àwọn obìnrin nílò láti pe ara wọn níjà máa kópa dáadáa síi nínú òṣèlú.”

Ó fi kun pé nǹkan tó ń mú kí àwọn obìnrin máa sá láti dupò òṣèlú kò kọjá pé àtàrí àjànàkú ni ọ̀rọ̀ òṣèlú, kìí ṣe ẹrù ọmọdé.

Bákan náà ló rọ àwọn obìnrin láti túnbọ̀ kára mọ́ kíkópa nínú òṣèlú nítorí tí gbogbo ènìyàn bá so ọwọ́ kọ́ àwọn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sípò òṣèlú ni yóò máa jẹ àǹfàní rẹ̀.

Funlola Akinrinde ní tí òun bá ní àǹfàní láti wọlé ìbò, òun máa ríi dájú pé òun mú ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ní òkúnkúndùn.