You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀rẹ́bìrin tó kọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sílẹ̀ yóò san $2,550 owó ‘gbà má bínú’ - Iléejọ́
Ile ẹjọ kan ni Uganda ti paṣẹ fun omidan kan to kọ ọrẹkunrin rẹ silẹ lairo tẹlẹ ko san owo gba mabinu fun ọkunrin ọhun.
Idajọ yii ko sẹyin iporuru ọkan to de ba ọkunrin ọhun lẹyin ti omidan naa dede kọ ọ silẹ.
Ṣaaju ni Richard Tumwine ti kọkọ na owo ti iye rẹ to $2,550, gẹgẹ bii owo ile ẹkọ afẹsọna rẹ, Fortunate Kyarikunda, lasiko ti ere ifẹ wọn ṣe n lọ dede.
Amọ lẹyin ti Kyarikunda ti sọ pe oun ko ṣe mọ lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti n ba ere ifẹ wọn bọ, ile ẹjọ naa ni ko da owo ile ẹkọ naa pada fun Richard.
Ile ẹjọ ọhun ni iwa jẹgudujẹra ni Kyarikunda wu bo ṣe kọ Richard silẹ lẹyin ti ọkunrin naa ti na obitibiti owo le lori.
Ṣugbọn Kyarikunda sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn obi oun lo paṣẹ pe oun ko gbọdọ fẹ Richard.
"Ko yẹ ki ọrẹbinrin gba owo lọwọ ọrẹkunrin mọ nigba to mọ pe awọn obi oun ko gba ki wọn fẹ ara wọn"
Gẹgẹ bii ohun ti ile ẹjọ sọ, ko yẹ ki Kyarikunda gba owo lọwọ ọrẹkunrin mọ niwọn igba to mọ pe awọn obi oun ko gba ki wọn fẹ ara wọn.
Ko sẹni to tii le sọ boya Kyarikunda yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ naa.
Wayi o, awọn onimọ kan ti sọ pe idajọ naa ko lẹṣe nilẹ nitori afẹsọna lasan ni awọn ololufẹ mejeji, wọn ko tii gbe ara wọn sile ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Ẹkọ imọ ofin ni Kyarikunda n kọ nile ẹkọ eyii ti Richard san owo rẹ.