You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ kògbó-kògbó méjìdínlọ́gbọ̀n kúrò ní Gaza lọ Egypt láti gba ìtọ́jú
Awọn ọmọ kogbo-kogbo mejidinlọgbọn ti wọn ko kuro nile iw-san al-Shifa lọjọ Aiku ni wọn ti de si Egypt lati gba itọju.
Dokita Mohamed Salama, to jẹ adari ẹke itọju awọn ọmọ ikoko nile iwosan al-Ahli Emirates ni ibode Rafah nibi ti wọn kọkọ ko awọn ọmọ naa lọ, sọ fun BBC pe oun ko mọ ibi ti awọn ọmọ naa n lọ ni pato ti wọn ba de Egypt.
Dokita Salama wi pe “igbimọ kan lati ileeṣẹ eto ilera lorilẹ-ede Egypt ni yoo tẹwọ gba wọn ti wọn yoo si fẹnuko lori ibi ti wọn yoo ko awọn ọmọ naa lọ”.
Gẹgẹ bi BBC ṣe sọ ṣaaju, minisita feto ilera ni Egypt ni wọn wi pe o ti wa ni papakọ ofurufu El-Arish nitosi ibode Egypt ati Gaza lati tẹwọ gba awọn ọmọ naa.
Idi to fi jẹ pe mejidinlogun ninu awọn ọmọ kogbo-kogbo mọkanlelọgbọn la ko lọ Egypt
Dokita Mohamed Salama ṣalaye fun BBC pe “awọn obi kan nile-iwosan al-Ahli Emirates lana (ọjọ Aiku) lati waa da tiwọn mọ ninu awọn ọmọ naa.
“A si ni ki wọn tọwọ bọwe pe wọn faramọ ki a ko awọn ọmọ wọn lọ Egypt fun itọju.
“Ọmọ kan wa nibi ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ, ti a ko si mọ awọn obi rẹ.
Ọmọ naa ṣi wa pẹlu wa nibi.
Awọn alaṣẹ eto ilera ni Gaza lo ni ki a wa nibi nitori pe ara rẹ ti balẹ, ko si nilo pe a n gbe e lọ fun itọju.
“Bakan naa ni a ni awọn ọmọ meji kan ti awọn obi wọn ko gba ki a ko wọn lọ Egypt fun itọju fun idi to han si awọn obi naa nikan.”
Dokita Salama wi pe awọn ọmọ mẹtẹẹta naa ni ara wọn ti balẹ lakoko ti a n ṣakojọ iroyin yii.
Ilé ìwòsàn Gaza al-Shifa ti di panpẹ́ ikú, ogúnlọ́gọ̀ kúrò - WHO
Ajọ eleto ilera agbaye WHO ti sapejuwe Ile iwosan al-Shifa niluu Gaza gẹgẹ bii panpẹ iku lẹyin ti wọn ṣe abẹwo si ibẹ.
Igbimọ kan ti awọn alasẹ Who lewaju ṣe abẹwo si ile iwosan naa, ti wọn si se ofintoto ipo ti ile iwosan naa fun wakati kan lẹyin ikọlu orilẹede Israel.
Igbimọ naa ni awọn ri ẹri bi ibọn ṣe sọ sẹ, ti wọn dẹ tun salabapade saare oku niwaju abawọle ile iwosan naa.
Ile iwosan al-Shifa lo jẹ ile iwosan to tobi ju lọ tẹlẹ niluu Gaza ki ogun to bẹrẹ.
WHO ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati gbe awọn eeyan to n gba itọju ni ile iwosan ati awọn osisẹ lọ si ibo miiran niluu Gaza, ti wọn si n pe idaduro ogun.
Bakan ni ile ijọba White House ti fesi si iroyin kan to jade ni Washington Post to ni Israel, Hamas ati ilẹ Amẹrika ti n jiroro lori igbesẹ ti yoo mu Ikọ ologun yoo fi awọn obinrin ati ọmọde ti wọn ji gbe ni Ọjọ Keje oṣu Kẹwaa, ti israel naa yoo si dawọ ogun duro fun ọjọ meje.
Agbẹnusọ White House ni ko sI ohun to jọ adehun naa sugbọn awọn sisẹ lati mu adehun kan waye.
Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ti wọgile ipe fun pe ki awọn dawọ ogun duro pẹlu Hamas, to si ni oun le gba pe ki awọn dawọ ogun duro fun igba diẹ ti Hamas ba tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ.
Ogunlọgọ eeyan paapa awọn to n gba itọju lo ti kuro ni ile iwosan al-Shifa lọjọ Satide. Awọn osisẹ ile iwosan naa sọ wọn ni ki awọn kuro ni agbegbe ile iwosan naa.
Akọroyin kan to wa ni ile iwosan al-Shifa sọ fun BBC pe awọn eeyan to wa ni ile iwosan naa bayii ni awọn eeyan to n gba itọju ti ko le rin ati awọn Dokita diẹ.
“A gbe ori wa soke, ti a si na asia funfun soke,” Khader, akọroyin to ti wa al-Shifa sọ fun BBC.
“O le pupọ ni alẹ ana. Iro ado ologun to n bu gbamu n dẹru bani pupọ. Awọn bugbamu fi iho silẹ si ara ogiri ile iwosan , ti si bo awọn eeyan mọlẹ.”
Saaju ,Ẹka eto ilera Hamas ni o to eeyan ọgọfa lo wa ni ile iwosan naa to n gba itọju ati ọpọ awọn ikoko ti ko ni iye.