Bí DSS kò bá wá nǹkan ṣe sí àwọn alágbara oníṣòwò epo tó ń képo pamọ́, ariwo lásán ní gbèdéke rẹ̀ - PETROAN

Ẹgbẹ awọn onile epo lorilẹede Naijiria, PETROAN ti bu ẹnu atẹ lu gbedeke wakati mejidinlaadọta ti ileeṣẹ agbofinro DSS gbe kalẹ fun awọn ontaja epo lati rii pe ọwọngogo epo dopin ni Naijiria.
Awọn onile epo bẹntiro ni Naijiria naa ni ariwo lasan lawọn DSS n pa o bi wọn ko ba lee wa awọn alagbara koṣeebawi to wa laarin awọn oniṣowo epo rọbi to n ko epo naa pamọ lai fẹ ta a fun awọn onile epo.
Alaga ẹgbẹ PETROAN lẹkun ila oorun, Sunny Nkpe sọ eyi di mimọ nigba to n kopa lori eto ileeṣẹ iroyin kan lọjọ Aje.
“Ẹ jẹ ki n sọ eyi laifọtape: bo ti wu ki ileeṣẹ agbofinro DSS ko ihalẹ bolẹ to, ko le yi ohunkohun pada. Bi ayipada yoo ba waye, lati orirun gan an ni yoo ti bẹrẹ. Awọn aladani to n ṣowo epo rọbi lo yẹ ki wọn wa lọ lati mọ ibi ti a ti n ri epo ra bayii.
“O di igba ti DSS ba ti mojuto awọn alagbara to wa laarin wọn , ki a to le ri atunṣe si ilana pinpin epo.”
O ni fun nnkan bii oṣu mẹfa bayii, ẹyọ epo kan ko de si ibudo ikepopamọsi to wa ni Port Harcourt.
Ki lo fa gbedeke DSS fun awọn ontaja epo

Lọjọbọ ni ileeṣẹ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ apapọ lorilẹede Naijiria, DSS paṣẹ fun awọn ontaja epo lorilẹede Naijiria ati ileeṣẹ ipọnpo Naijiria, NNPC Limited lati tete wa ojutu si wahala ọwọngogo epo to n da awọn ọmọ Naijiria laamu bayii.
Alukoro DSS, Peter Ifunaya ni bi ayipada ko ba de ba ọrọ ọwọngogo epo yii, awọn yoo gbe igbesẹ ti ara wọn.
Epo bẹntiro ti di goolu lorilẹede Naijiria bayii pẹlu bi o ṣe n di iniria fun awọn ọ̀mọ Naijiria lati rii fun lilo. Ẹwẹ ọwọgogo lawọn ileepo to n ri epo naa ta n ta ni owo gọbọi to to igba ati aadọta naira (N250/litre) dipo naira mọkandinlaadọsan lori lita kan (N169/Litre) ti ijọba fi si.












