Ǹjẹ́ o mọ ẹ̀tọ́ rẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀?Wo àwọn ǹnkan tó o gbọdọ̀ retí

Ǹjẹ́ o mọ ẹ̀tọ́ rẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀?Wo àwọn ǹnkan tó o gbọdọ̀ retí

Laipẹ yii ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria dajọ pe, ki agbara ati aṣẹ lori owo to n wọle si apo awọn ijọba ibilẹ, pada sọwọ wọn.

Ṣaaju idajọ naa, ọpọ awọn gomina lo n dari bi awọn ijọba ibilẹ sẹ n na owo wọn, ti wọn si tun n yan alaga fun wọn.

Lati igba igba ti idajọ naa ti waye si ni awọn gomina kan ti n fi apa jaamu lori rẹ.

Bẹẹ ni awọn ọmọ Naijiria kan n dun nu si idajọ ọhun.

Amọ, kii gan-an ni anfaani to wa ninu ominira ijọba ibilẹ, fun araalu?

BBC ba Oloye Abass Alesinloye, Alaga ijọba ibilẹ Oluyole niluu Ibadan nigba kan, sọ pe ọpọ ijọba ibilẹ lo n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ, ṣugbọn ti awọn eeyan to n gbe niru awọn ijọba ibilẹ bẹẹ ko jẹ anfaani owo ti wọn n pa fun ijọba.

Alesinloye sọ pe lara awọn ojuṣe ijọba ibilẹ fun araalu ni ipese awọn ohun amayedẹrun bii opopona to dara, omi, ati aabo ilu.

Lara rẹ tun ni ipese awọn olukọ ni awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ti ko ti si olukọ.

Kini yoo ṣẹlẹ si awọn ipinlẹ ti ko ni alaga ijọba ibilẹ?

Lọwọlọwọ, ijọba ibilẹ 774 lo wa ni Naijiria, ṣugbọn kii sẹ gbogbo wọn lo ni alaga ti ilu dibo yan.

Lara iru awọn ipinlẹ bẹẹ ni Kwara, Anambra, Bauchi, Kogi, ati awọn mii.

Ọjọgbọn Gbade Ojo to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ofin ni Fasiti Ilorin ṣalaye pe, ijọba apapọ ko ni fun iru awọn ijọba ibilẹ ti ko ni alaga ti ilu dibo yan, ni owo to tọ si wọn, titi wọn o fi ṣe nnkan to yẹ.

Eyi tumọ si pe, gomina kọọkan gbọdọ sẹ eto idibo ni kiakia.

Kini yoo ṣẹlẹ si awọn ijọba ibilẹ LCDA ti awọn ipinlẹ kan da silẹ?

Awọn gomina kan da awọn ijọba ibilẹ aladani, ti wọn n pe ni LCDA, silẹ.

Pẹlu idajọ tuntun yii, ki ni yoo sẹlẹ si wọn?

Ọjọgbọn Gbade Ojo sọ pe ọjọ iwaju iru awọn ijọba ibilẹ bẹẹ ko da ju, nitori pe wọn ko si labẹ ijọba apapọ.

“Awọn ijọba ipinlẹ bii Eko, Oyo, Osun, Ogun, ati Ondo, to da wọn silẹ, ni yoo maa gbọ bukata wọn.

“O si ṣeeṣe ki iṣejọba awọn LCDA ọhun wa sopin bayii.”