Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń fi èèyàn ṣòwò ẹrú ní Ibadan, dóòlà èèyàn 84

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti tẹ awọn kan to n fi eeyan ṣe owo ẹru niluu Ibadan.

Eeyan mẹrinlelọgọrin ati ọmọde kan ni ọlọpaa doola ninu ile ti awọn afini ṣòwò naa ko wọn si lagbegbe Orogun fun ọpọ ọjọ.

A gbọ pe pupọ ninu awọn ẹni ti ọlọpaa doola naa lo jẹ ọmọ orilẹede Democratic Republic of Congo ti wọn tan wa si Naijiria pẹlu ẹtan pe wọn yoo fun wọn ni iṣẹ.

Iroyin ni obitibiti owo dọla lawọn afurasi naa gba lọwọ awọn mọlẹbi awọn eeyan ti ọlọpaa doola ọhun pẹlu ẹtan.

Awọn ti ọlọpaa doola ti wa ni ọọfisi ọlọpaa to wa ni Akinyele, niluu Ibadan bayii fun iwadii to peye.

Ọpọ araalu lo peju si adugbo naa lasiko ti ọlọpaa n doola wọn kuro ninu ile ọhun.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa duro wamuwamu lagbegbe ọhun lati ri daju pe aralau ko fi ofin si ọwọ ara wọn nibẹ.

Wayi o,, titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko tii sọ nnkankan lori iṣẹlẹ naa.