You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
" Iná orí fóònù àti 'Torchlight' ni dókítà fi gbẹ̀bí, rán ojú ara mi tó ya lásìkò ìbímọ nílé ìwòsàn UCH"
Ile iwosan ẹkọsẹ isegun UCH jẹ ile iwosan nla nilẹ Naijiria ati niwọ oorun Afirika to gbaju gbaja julọ fun iwosan igbalode.
Yatọ si pe ile iwosan naa n kọ awọn dokita ati Nọọsi nipa ẹkọsẹ imọ isegun to dantọ, ọpọ awọn irinsẹ iwosan igbalode lo wa nile iwosan naa, eyi to maa n gbalejo ọpọ alaisan yika iwọ oorun ilẹ Afirika.
Amọ, kinni kan ba Àjàò ile iwosan naa jẹ, ti apa rẹ fi gun ju itan lọ, nnkan naa si ni ina ọba ti ko si nile iwosan naa fun osu mẹrin gbako.
Aisi ipese ina ọba naa waye ni osu kẹwaa dun 2024 si osu keji ọdun 2025.
Eyi ri bẹẹ, bi ajọ to n pese ina ọba ni ẹkun Ibadan, IBDEC se ja ina ile iwosan naa lori ẹsun pe o jẹ gbese 495 milliọnu Naira.
Lasiko ti isẹlẹ naa waye, ọpọ alaisan lo sa kuro nile iwosan naa, awọn osisẹ gan ka ọwọ ko, lai le sisẹ oojọ wọn.
Awọn osisẹ ilera ni wọn n lo atupa, Torch light lati sisẹ, paapaa isẹ abẹ, ti ọpọ alaisan si ni ooru amuju fẹ pa awn tori aisi ina nile iwosan nla naa.
Ọpọ awọn osisẹ, alaisan atawọn akẹkọọ to n kọ nipa imọ isegun lo figbe ta lori ewu nla to wa nidi aisi ina ọba nile iwosan naa.
Amọ lẹyin osu mẹfa ti laasigbo naa ti n waye, ijọba apapọ da si ọrọ naa, ti ina ọba si pada sile iwosan UCH.
"Ẹẹmeji ni aisi ina ọba se akoba fun ilera mi, koda, n ko le se isẹ abẹ lasiko to yẹ"
BBC wa se awari awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa, paapaa awọn to sisẹ abẹ, lati mọ nnkan ti oju wọn ri lasiko ti ko si ina ọba nile iwosan UCH.
Nigba ti wọn n ba wa sọrọ, Omidan Fatimo Jinadu salaye pe ẹẹmeji ni isẹlẹ aisi ina ọba nile iwosan UCH se akoba fun oun.
"Osu kẹfa ọdun 2024 ni isẹlẹ aisi ina ọba nile iwosan UCH kọkọ se akoba fun mi, ti n ko si le se isẹ abẹ naa titi di osu kẹwa dun naa.
Igba keji ti aisi ina ọba yii tun se akoba fun mi ni osu kejila ọdun 2024 ti oun ni ipenija ilera, ti ko si si ina ọba nile iwosan naa.
Ko si ina ba nile iwosan naa lati seto ẹjẹ to yẹ fun mi."
"Ina 'Torchlight' ati Foonu ni wọn fi gbẹbi fun mi, ti wọn fi ran oju ara mi to fa ya lasiko ibimọ"
Ẹnikeji to ba BBC sọrọ, Adetutu Ogunsanwo ni oun lọ bimọ sile iwosan UCH lasiko ti ko si ina ọba, ti oju oun si ri mabo.
"Ina onibatiri alagbeka ati ina ori ẹrọ ilewọ foonu ni wọn fi gbẹbi fun mi, oju ara mi ya pupọ, ti mo si n jaya pe se ina ilewọ onibatiri yii ni wọn yoo fi ran oju ara mi to ya.
Se ni dokita kan n ran oju ara mi lọ pẹlu ina ori foonu, koda, ko si nnkan to ni ki ohun gbogbo mase yiwọ lọjọ naa."
"Emi ati Olukọ mi n wa ibudo ayẹwo kiri lọgba UCH lati kọ isẹ amọ ko si eyi to ni ina ba"
"Emi ati Olukọ mi n wa ibudo ayẹwo kiri lọgba UCH lati kọ isẹ amọ ko si eyi to ni ina ba"
Aweda Olatunji ni kii se awọn alaisan nikan ni isẹlẹ naa se akoba fun, koda, o tun se akoba fun awọn akẹkọọ Nọọsi ati dokia nile iwosan naa.
Koda, ọkan lara awọn akẹkọọ naa ni oun ranti asiko naa, ti oun ati olukọ oun n wa ibudo ayẹwo kiri ti awọn ti fẹ kọsẹ.
Nibayii, wakati mẹjọ pere nile iwosan UCH fi n lo ina ọba bayii, lẹyin ti ijọba apapọ da si aawọ ile iwosan naa ati ajọ amunawa, ti ina ọba si pada sibẹ.
Sibẹsibẹ, ko si idaniloju pe ipese ina ọba sile iwosan UCH fun wakati mẹjọ ni oojọ fẹsẹ rinlẹ.