Jìbìtì lu òṣeré tíátà, ó ní gbogbo owó òun ní báńkì ti pòórá lójijì láìmọ̀

Osere tiata kan to sẹsẹ n didelẹ, Zainab Bakare ti figbe bọnu loju opo Instagram rẹ pe gbogbo owo ti oun fi pamọ sile ifowopamọ ti poora lojiji.

Osere tiata naa to n tara poro pe nibo ni oun ti fẹ bẹrẹ igbe aye oun bayii fi ikede naa sita lọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bi Zainab ti salaye, gbogbo owo ti oun fi pamọ si apo asunwọn oun nile ifowopamọ olokoowo igbalode kan lo ti poora lojiji.

O ni awọn onijibiti kan lo n da oun loro bẹẹ, ti wọn si lo ibudo abanigbowo lori ẹrọ, ta mọ si POS lati gba owo naa jade.

O sọ siwaju si pe gbogbo igbiyanju oun lati jẹ ki ile ifowopamọ ti oun n lo naa wa owo yii jade lo ja si pabo.

“Mo kan si ile ifowopamọ ti mo n lo lati fi to wọn leti pe awọn eeyan kan ti gba owo mi ti mo fi pamọ sọdọ wọn jade laimọ.

Amọ se ni ile ifowopamọ naa sọ fun mi pe o nira lati tọpasẹ ẹrọ POS ti awọn onijibiti naa lo lati gba owo mi jade.

Wọn tun wa sọ fun mi pe ki n lọ ni suuru fun ọjọ mẹwa si ọgbọn ọjọ amọ bawo ni mo se le ni idaniloju pe wọn yoo ri ojutu si isoro yii?”

Osere tiata naa fikun pe owo olowo ni awọn owo naa, nigba ti awọn to ni owo ba si n tabuku oun lori ayelujara, ọpọ ọta oun ni yoo maa se ẹlẹya oun ni ẹgbẹ kan.

Wayi o, awọn akẹẹgbẹ Zainab lagbo tiata ti bẹrẹ si ba oserebinrin ọhun daro lori adanu to baa.

Nigba to n da si ohun ti Zainab kọ soju opo tiata rẹ, Gbajumọ osere kan, Jamiu Azeez ni ki ọmọbinrin naa lọ si olu ileesẹ banki to ba dowopọ naa lati fi igbe ta.

O fikun pe gbogbo wahala tro ba ba wọn fa lọhun ni ko fi ẹrọ ayaworan foonu rẹ, ko si gbe sori ayelujara, ti awọn yoo si bẹrẹ si pariwo wọn fun araye.

Bakan naa ni Bimpe Akintunde gba Zainab nimọran pe ko lọ beere fun ẹkunrẹrẹ akọsilẹ bo se sanwo wọle ati bo se gba owo jade nile ifowopamọ ọhun.

O fikun pe lẹyin eyi ni ko wa lọ fi ẹjọ banki naa sun lọdọ awọn ọlọpaa nitori iwa lilu jibiti naa ti kọja eyi ti eeyan yoo maa pariwo lori ayelujara lasan.