You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni ìjìyà fún Mùsùlùmí tó bá ní ìbálòpọ̀ lọ́sàn-án àwẹ̀?
Awẹ gbigba jẹ ọkan lara opo marun-un ti ẹni to ba jẹ musulumi gbọdọ gbagbọ ninu rẹ.
Lasiko awẹ, awọn musulumi ko gbọdọ jẹun, mu omi tabi sunmọ iyawo wọn lati igba ti alifajari ba ti yọ titi di igba ti oorun maa fi wọ.
Idi ti awẹ gbigba ṣe pọn dandan fun awọn ẹlẹsin Islam ni ki agọ ara wọn le ri ayipada si ilana to mọ.
Bakan naa, wọn yoo si tun gba laada lọdọ Ọlọrun ti wọn ba pa gbogbo ofin awẹ gbigba naa mọ daadaa.
Ọpọlọpọ adojukọ ni awọn to ba ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo tabi ṣẹṣẹ bẹrẹ ibalopọ maa n ni lasiko ti awẹ ba n lọ lọwọ.
Ibalopọ laaarin lọkọ laya lọsan lasiko awẹ ki ṣe ẹṣẹ kekere rara - Onimọ ẹsin Islam
Ọpọ idile to ti wa ninu igbeyawo fun ọpọ ọdun, naa maa n ṣe awọn asiṣe kọọkan to nii se pẹlu ibalopọ.
Amọ awọn ijiya wo lo wa fun ọkunrin to ba mọọmọ ni ibalopọ pẹlu iyawo rẹ lọsan awẹ?
BBC ba Halliru Abdullahi Maraya, tii se Onimọ nipa ẹsin Islam sọrọ, to si ṣalaye pe ibalopọ laaarin lọkọ laya lọsan lasiko awẹ ki ṣe ẹṣẹ kekere rara.
"Aawẹ osu meji ni ọkunrin to ba sun mọ aya rẹ ni ọsan aawẹ fi san pada"
Abdullahi ni ti ọkunrin ba sun mọ iyawo rẹ lọsan awẹ, o ti daran kafaara eyi to gbọdọ san pada pẹlu awẹ oṣu meji.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe onitọhun maa gba awẹ oṣu meji lera wọn laini dawọ duro nitori ohun to le fi tan ẹṣẹ rẹ niyi.
Ti eeyan ba pa awẹ jẹ nitori aisan tabi ilera kan, iru eeyan bẹẹ yoo bọ awọn alaini, to si gbọdọ bọ awọn alaini naa fun iye ọjọ ti ko fi gba awẹ.
Ti o ba si fẹ san aawẹ pada, oṣu meji ni yoo fi san awẹ ọjọ meji to ba jẹ.
Jija awẹ nigbakigba to ba wu eniyan jẹ nnkan ti ko jẹ itẹwọgba ninu ẹsin Islam, ti ijiya to gbopọn si wa fun-un paapaa ti aatọ ọmọkunrin ba jade lara rẹ.
Awọn aṣiṣe yii ni awọn to ba ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo ṣaaju asiko awẹ maa n koju.