You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Tinubu tún ti tẹkọ̀létí ròkè òkun, ipò wo ni Tinubu wà láàrín àwọn Ààrẹ tó rìnrìnàjò jùlọ?
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti bẹre isinmi lẹnu iṣẹ ọlọdọọdun rẹ fun ti ọdun 2025, o si ti tẹkọleti roke okun bayii.
Ninu atẹjade ti olubadamọran agba fun aarẹ lori iroyin, Bayo Onanuga, buwọlu fun awọn akọroyin, o ni aarẹ yoo lo ọjọ mẹwaa fun isinmi naa, ti yoo si lọ lati orilẹede France si Ilẹ United Kingdom.
"Aarẹ Bola Ahmed Tinubu yoo kuro ni ilu Abuja ni Ọjọbọ, Ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹsan an ọdun 2025 fun isinmi ni Yuroopu ,
"Ọjọ mẹwaa ni yoo fi ṣe isinmi yii. Aarẹ yoo lo asiko yii ni ile France ati UK ko to pada si orilẹede Naijiria."
Aarẹ Tinubu ma n rin irinajo daada, ti eyi si jẹ ọkan ninu awọn irinajo to ma n lọ lati igba to ti bọ sipo ni oṣu karun un ọdun 2023.
Isinmi ọlọjọ mẹwaa yii waye lẹyin ti aarẹ ti kọkọ gba ọkan ni oṣu kẹwaa ọdun 2024.
Irinajo Aarẹ Tinubu lati Oṣu Karun un ọdun 2023
Gẹgẹ bii Punch ṣe gbe sita, laarin oṣu mẹtadinlogun akọkọ ti aarẹ Tinubu lo lori oye, irinajo mọkanlelogoji loun ati igbakeji ti rin kaakiri orilẹede mẹrindinlọgbọn, ti wọn si lo ọgọsan ọjọ lapapọ loke okun.
Eyi ti o lọ gbeyin ni orilẹede Brazil ni oṣu kẹjọ ọdun 2025, nibi to ti lọ pade Aarẹ Luiz Inacio Lula da Sliva.
Aarẹ Tinubu ti lọ awọn orilẹede bii United States, France, di United Kingdom, China, South Africa, Germany, Tanzania, ati United Arab Emirates.
Ni oṣu kinni ọdun 2025, Tinubu lọ fun ipade awọn olori orilẹede Afrika ni Dar es Salaam, lorilẹede Tanzania.
Ni oṣu Karun un ni ọdun 2025, o lọ si Rome, lorilẹede Italy, fun ayẹyẹ iyansipo Pope Leo XIV.
Ni oṣu kẹfa si ikeje ni ọdun 2025, aarẹ lọ si Saint Lucia fun imunadoko ajọsepọ pẹlu awọn orilẹede Caribbean.
Bakan naa ni oṣu kẹfa si ikeje ni ọdun 2025,Aarẹ tun gbera lọ si orilẹede Brazil fun imunadoko ajọsepọ lori eto ọgbin.
Ni oṣu kẹjọ, Aarẹ wa nibi ayẹyẹ iburawọlw Aarẹ John Dramani Mahama lorilẹede Ghana.
Ni oṣu kẹjọ yii naa, Aarẹ lọ si UAE, to si gba ibẹ lọ si Japan.
Aarẹ tun pada lọ si orilẹede Brazil fun igbakeji ni oṣu kẹjọ.
Bayii ni awọn aarẹ yooku ṣe rin irinajo?
Awọn ọmọ Naijiria kan gbagbọ pe Aarẹ Bola Tinubu ko ni pẹ di aarẹ orilẹede Naijiria to rin irinajo ju awọn aarẹ yooku ti wọn ti jẹ ṣaaju.
Ṣugbọn ẹ jẹ ka fi wo awọn irinajo awọn aarẹ bi Goodluck Jonathan, oloogbe Muhammadu Buhari ati Olusegun Obasanjo.
Ileeṣẹ iroyin Dailypost, Aarẹ Goodluck Jonathan rin irinajo daada, to si ni lati ṣe ileri pe oun yoo dinku.
Ninu iwadii wọn, Goodluck Jonathan rin irinajo o kere ju ogun igba laarin oṣu mọkanla akọkọ rẹ ni ọdun 2012.
Lasiko iṣejọba Aarẹ Buhari, yatọ si awọn irinajo fun itọju, o rin irinajo ni mẹtalelaadọta gẹgẹ bii ọdun 2023 ṣe gbe sita.
Aarẹ nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo rin irinajọ fun igba 97 lasiko iṣejọba laarin ọdun 1999 si 2007.