'Láti ìgbà tí ọkọ mi ti nàmí fún ìgbà àkọ́kọ́ ni kò ti dáwọ́ dúró'

'Láti ìgbà tí ọkọ mi ti nàmí fún ìgbà àkọ́kọ́ ni kò ti dáwọ́ dúró'

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí apá kò bá ṣe é sán, níṣe ni ènìyàn máa ń ka lórí.

Èyí ló farapẹ àwọn abílékọ́ yìí tí wọ́n ti fi ìgbà kan wà nílé ọkọ ṣùgbọ́n tí wọ́n ti kúrò báyìí tí wọ́n sì ń dá àwọn ọmọ wọn tọ́.

Nígbà tí wọ́n ń bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀, wọ́n ṣàlàyé pé ohun tí ojú àwọn rí nílé ọkọ àwọn ló jẹ́ kí àwọn digbá dagbọ̀n àwọn láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò ayé .

Wọ́n ní yàtọ̀ sí pé ọkọ àwọn kìí ṣe ìtọ́jú ilé nígbà tí àwọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lílù kìí tó wíwọ́ fún àwọn ni àwọn ṣe bá ẹsẹ̀ àwọn sọ̀rọ̀.

Bákan náà ni wọ́n sọ ìrírí wọn láti ìgbà tí wọ́n ti kúrò nílé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nílé àwọn ọkọ wọn.

Ẹ̀wẹ̀, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta,ọjọ́ Kẹẹ̀dógbọ̀n, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni ayájọ́ ìdènà fífi ìyà jẹ́ àwọn obìnrin ní àgbáyé.

Ní ọdún 1979 ni àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé yà ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ láti máa ṣe ìpolongo lórí ìdènà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin.

Wọ́n ya ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ láti fi ṣe ìrántí fún àwọn ènìyàn láwùjọ pé kò tọ́ láti máa fìyà àwọn obìnnrin.

Àmọ́ síbẹ̀ náà ìwà fífi ìyà jẹ́ àwọn obìnrin kò ìtíì wá sópin lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélógójì tí wọ́n ti ya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ láti máa ṣe ìpolongo yìí.