Wọn ti sìn òkú èèyàn mẹ́tàlá tí àwọn afurasí agbébọn ṣekú pa ni Taraba

O to eeyan mẹtala ti wọn padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn afurasi agbẹbọn ṣe ikọlu si agbegbe Karekuka ni ipinlẹ Taraba lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun BBC News pe ogunlọgọ eeyan miiran to farapa nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si wa ni ilewosan ti ijọba apapọ to wa ni Jalingo.

Ẹto isinku awọn ologbe naa lo ti waye ni ilana ẹsin Musulumi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn olugbe agbegbe naa ni wọn mu ole to ṣe wọn ni ijamba, ti wọn si ṣeku pa, eyi lo bi awọn akẹgbẹ ninu, ti wọn si gbera lati gba ẹsan, ti wọn si ṣeku eeyan mẹtala.

Iroyin tun ni awọn afurasi gbegbọn kan tun ti ṣe ikọlu si agbegbe Gidado ni ipinlẹ Tarapa, sugbọn ko si ẹnikẹni niluu naa.

SP Abdullhi Usman ni awọn ẹsọ alaabo ti bale si agbegbe na lati ṣe iwadi.