Queen Elizabeth II: Àwọn ètò tó wà fún títẹ́ òkú Ọbabìnrin ní ìtẹ́ ẹ̀yẹ àti ìsìnkú rẹ̀

Ọbabinrin Elizabeth ti waja, eyi to n fi opin si isejọba to tii p julọ ninu itan ilẹ Gẹẹsi.

Ọbabinrin Elizabeth ku wọọrọwọ, ti awọn ẹbi rẹ si rọgba yika ni Balmoral Castle to wa ni orilẹede Scotland.

Ni awọn ọjọ diẹ to wa niwaju, awọn ohun ta maa reti ree fun eto titẹ oku rẹ ni itẹ ẹyẹ ati isinku rẹ, nibayi ti orilẹede n se ẹyẹ fun.

Titẹ oku Ọbabinrin ni itẹ ẹyẹ

Lẹyin ti wọn ba gbe oku rẹ de ilu London, wọn yoo tẹ oku Ọbabinrin nitẹ ẹyẹ ni gbọngan Westminster fun ọjọ mẹrin gbako saaju isisnku rẹ, eyi ti yoo fun awọn araalu ni anfaani lati to lọwọọwọ wo oku rẹ.

Gbọngan nla naa lo jẹ ọlọdun gbọọrọ julọ ni aafin Westminster, to wa ni aarin gbungbun isejọba ilẹ Gẹẹsi.

Mọlẹbi ọba ti wọn tẹ nitẹ ẹyẹ gbẹyin ninu gbọngan naa ni iya Ọbabinrin naa eyi to waye lọdun 2002, nibi ti awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna igba ti to lọwọọwọ lati wo posi rẹ.

Wọn yoo gbe posi Ọbabinrin Elizabeth si ori pepele onipako kan, lati tẹ nitẹ ẹyẹ labẹ orule ti wọn fi igi Gẹdu se lati saa onka ọdun 11th Century. Igun kọọkan pepele naa ni awọn ologun lati awọn ọ̀wọ́ ileesẹ ologun to n sisẹ lọdọ idile ọba.

Wọn yoo wa gbe oku Ọbabinrin wa si gbọngan Westminster lati aafin Buckingham ni tito lọwọọwọ, tawọn ologun to n se ẹyẹ yoo si tẹle pẹlu awọn idile ọba.

Awọn eeyan yoo ni anfaani lati wo bi wọn se n gbe posi rẹ lọ pẹlu tito ni ọwọọwọ lawọn oju popo, ti wọn yoo si tun ri awọn mohunmaworan gbangba-gbangba sawọn ibudo igbafẹ to jẹ ti ijọba nilu London.

Posi Ọbabìnrin Elizabeth ni wọn yoo da asọ daradara bo nibamu pẹlu ipo ọla rẹ, ni kete to ba si ti de gbọngan Westminster, wọn yoo gbe ade ọba, ọpa asẹ ati ami idamọ ipo ọba rẹ le posi naa.

Ni kete ti posi naa ba ti wa nibi to yẹ ninu gbọngan naa, ni wọn yoo se isin idagbere ranpẹ. Lẹyin eyi ni wọn yoo gba awọn araalu lati wọle.

Igba wo isinku Ọbabinrin Elizabeth?

Isinku alarinrin fun Ọbabinrin nireti wa pe yoo waye ni Westminster Abbey, eyi ti ko to ọsẹ meji si asiko yii, amọ aafin Buckingham ni yoo kede ọjọ ti yoo jẹ.

Abbey ni ile ijọsin ọlọjọ gbọọrọ nibi ti wọn ti maa n gbe ade le awọn Ọba ati Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi lori, to fi mọ ayẹyẹ iwuye Ọbabinrin Elizabeth to waye lọdun 1953, ati ibi to ti se igbeyawo pẹlu Ọmọọba Philip lọdun 1947.

Amọ isin idagbere fun oku ko waye nile ijọsin naa lati onka ọdun 18th Century, bi o tilẹ jẹ pe wọn se isin idagbere fun iya ọba lọdun 2002.

Awọn asaaju orilẹede jakejado agbaye si ni yoo maa dara pọ mọ awọn idile ọba lati se iranti igbe aye ati isisẹ sin ọmọniyan ti Ọbabinrin Elizabeth ti se. Awọn eekan oloselu atawọn Olootu Ijọba tẹlẹ naa ko si ni gbẹyin nibẹ.

Isin naa yoo bẹrẹ ni kete ti wọn ba ti fi kẹkẹ ẹlẹsin alaranbara tawọn ọmọ ogun ofurufu gbe oku Ọbabinrin Elizabeth lati gbọngan Westminster wọ ile ijọsin Westminster Abbey.

Ọdun 1979 ni wọn foju kan kẹkẹ ẹlẹsin pẹlu ibọn naa kẹyin lasiko eto isinku ibatan Ọmọọba Philip tii se ọlọla ti Mountbatten, eyi ti awọn awakọ oju omi mejilelogoje lati ileesẹ ologun oju omi seto.

Awọn agbaagba lati idile ọba, to fi mọ ọba tuntun, lo seese ko to lọwọọwọ pẹlu wọn.

O si seese ko jẹ pe olori ijọ Westminster, David Hoyle, nigba ti Bisọọbu agba fun ijọ Canterbury, Justin Welby, yoo maa se iwaasu. Olootu ijọba tuntun ni UK, Liz Truss, si lo seese ki wọn ni ko wa ka ẹsẹ bibeli kan nibi isisnku naa.

Lẹyin isin idagbere, wọn yoo tun posi Ọbabinrin Elizabeth pẹlu tito lọwọọwọ lati ile ijọsin Abbey lọ si Wellington Arch, to wa ni ibudo igbafẹ Hyde Park ni London, ko to di pe wọn gbe lọ si Windsor pẹlu ọkọ agboku.

Posi ara Ọbabinrin Elizabeth ni yoo bẹrẹ irinajo ikẹyin rẹ ni ọsan ọjọ naa lọ si ile ijọsin St George's Chapel to wa ni aafin Windsor Castle.

Ọba tuntun ati awọn agbaagba ni idile ọba nireti wa pe yoo dara pọ mọ titi ni ọwọọwọ ni gbagede Quadrangle to wa ni aafin Windsor, ko to di pe wọn gbe posi naa wọnu ijọ St George fun isin ikẹyin.

Ile ijọsin St George's Chapel ni awọn idile ọba saba maa n mu fun ayẹyẹ igbeyawo, isọmọlorukọ ati isinku. Ibẹ si ni Duke ati Duchess ti Sussex, Ọmọọba Harry ati Meghan gan ti se igbeyawo, ti wọn si tun se isinku ọkọ Ọbabinrin Elizabeth to ku, Ọmọọba Philip ninu ijọ naa.

Wọn yoo gbe ara Ọbabinrin Elizabeth si itẹ oku awọn idile ọba, ko to di pe wọn sin sinu ọgba ijọ King George VI memorial chapel, to wa ni ijọ St George.