Queen Elizabeth II: Wo àwòrán bí àwùjọ àgbáyé ṣe ń dárò ikú Ọbabinrin

Kaakiri orilẹede agbaye ni isẹ ibanikẹdun ti n wa lẹyin iku ọba ilẹ Gẹẹsi, Ọbabinrin Elizabeth to papoda.

Wọn ti fa ọpọ asia de idaji lawọn ibudo lorisirisi, to fi mọ ile ijọba Amẹrika ati ileesẹ ijọba ni Washington DC.

Awọn ero ti n kora jọ pọ lati se idaro, ti wọn si n gbe ododo silẹ ni iranti Ọbabinrin Elizabeth.

ba to ti pẹ lori itẹ julọ ku ni aafin Balmoral lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun, lẹyin to jọba fun aadọrun ọdun.

Aarẹ Joe Biden lọ si ileesẹ asoju ijọba Gẹẹsi nilu Washington lati fi ọwọ si iwe ibanikẹdun.