You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Efuoma Amos: Ẹ̀bùn láti ọ̀run wá ni, àwọn obìnrin ma ń wọ́ tẹ̀lé mi ni láti kékeré
"Igba miran to ba sun, maa ma wo pe ṣe emi ni Ọlọrun ṣe iyanu yii fun".
Amos to kẹkọ jade nipa imọ ẹrọ kọmputa sayẹnsi ṣalaye pe awọn obinrin ma n wa ni ikawọ oun ni, oun kii tiraka lati ni wọn.
Ọrọ arakunrin Efuoma Amos ni gbogbo eniyan fi bọnu lori ayelujara lẹyin to fi fọto ti oun ati iyawo afẹsọna rẹ ya (pre-wedding) rẹ sita ṣaaju igbeyawo wọn.
Ohun ti o mu ki awọn eniyan maa sọrọ ni bi ọkunrin naa ko ṣe ga rara, to si tun fẹ ẹni to ga juu lọ fiofio.
Amos to kẹkọ jade nipa imọ ẹrọ kọmputa sayẹnsi lo ba BBC Pidgin to si ṣalaye pe awọn obinrin ma n wa ni ikawọ oun ni, oun kii tiraka lati ni mọ.
O ni ẹbun ti Ọlọrun fun oun ni nitori lati igba ti wọn ti bi oun, ko ṣoro fun oun lati ri obinrin.
''Awọn to ga gan an, Ọlọrun o fun wọn ni nkan to fun mi, kii ṣe juju tabi oogun, wọn kan fẹran mi.''
''Igba ti mo n sin orilẹede mi lọwọ ni Ebonyi, obinrin to rẹwa julọ ni ibẹ, ti temi ni, ti o de ki n ṣe ọrọ owo, wọn kan fẹran mi ni.''
"Bi a ṣe pade ọkọ mi re e..."
Iyawo Amos ni ọrọ woli ni oun tẹle wa ni igba akọkọ ti oun ri ọkọ oun.
Mo lọ si ile ijọsin ni wọn ri iran si mi, ti wọn si ni ki auntie mi wa pẹlu mi, bi a ṣe ri ara wa ni yẹn laarin oṣu mẹfa ni a fẹ ṣe igbeyawo.
''Ni aye yii Ọlọrun da wa yatọ ni, awọn miran ga, awọn miran ko si ga, onikaluku abi tirẹ lara.''
''Ọkọ mi jẹ eniyan to ni iwa pẹlẹ, a ma n ṣere, to si ni ọyaya, ko si si oun ti mo fẹ ti kii fun mi.''
''Igba ti mo fẹ ṣegbeyawo, awọn obi mi ko tako ọkọ mi nitori pe o jẹ ẹni kukuru, niṣe ni wọn gbaruku ti mi''
Bawo ni igbeyawo naa ṣe n lọ?
Ọga Amos ni igbeyawo naa dun mọ oun de ibi gongo ookan aya oun.
''Gbogbo igba ti mo ba ri iyawo mi ni inu mi ma n dun''.
''Igba miran to ba sun, maa ma wo pe ṣe emi ni Ọlọrun ṣe iyanu yii fun.''
''Adura mi nipe ẹni to ba fẹ da igbeyawo wa ru ko ni mọ ọna ọdọ wa.''
Ọga Amos to sọrọ nipa igbeyawo rẹ akọko to fori sanpọn ni oun ko ni ibanujẹ kankan nitori gbogbo ohun ti oun la kọja ti da ohun ẹyin.
''Awọn miran tilẹ sọ pe mi o le ri iyawo mọ nitori iyawo mi akọkọ to fimi silẹ lọ,amọ a dupẹ lọwọ Ọlọrun to ṣeyanu ninu aye mi."