George Floyd: Ṣé ìdánilékọ̀ọ́ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ lè mú àdínkù bá ìwà ipá àwọn ọlọ́pàá sí aráàlú?

Ọlọpaa kan to jẹ alawọ funfun yoo foju bale ẹjọ ninu ọsẹ yii lorilẹ-ede Amẹrika lori iku George Floyd to jẹ alawọ dudu.

Lẹyin awọn ifẹhonuhan to tẹle iku okunrin naa, oriṣiriṣi awọn atunto ni ile igbimọ aṣofin Amẹrika ti ṣe kí ayipada rere le ba ileeṣẹ ọlọpaa.

Ṣugbọn ṣe awọn atunto yìí, idanilẹkọọ ati ìmọ ẹrọ lè mú ayipada rere ba ileeṣẹ ọlọpaa Amẹrika bi?

Ni báyìí tí igbẹjọ Derek Chauvin ti wọn fẹsun kan pe o tẹ George Floyd lọrun pa yóò bẹrẹ, a ṣe àgbéyẹ̀wò bi iwọde, ẹrọ ayàwòrán ati imọ ẹrọ ṣe ni ipa sí ninu oju tí àwọn ọlọpaa alawọ funfun fi n wo awọn eeyan dúdú l'Amẹrika.

Idanilẹkọọ ojuṣaju

Idanilẹkọọ yìí jẹ eyiti wọn fi n wo awọn agbofinro nipa ojú tí wọn fi n wo èèyàn kí wọn tó gbé ìgbésẹ̀ ti wọn n gbe.

Iwadii ijinlẹ kan ti wọn ṣe nílùú Philadelphia fi hàn pé, awọn ọlọpaa yinbọn lu èèyàn mọkandinlọgbọn ti wọn gbagbọ pe wọn ni ibọn lọwọ, marundinlọgbọn ninu awọn èèyàn náà ló jẹ alawọ dúdú.

Iwadii náà fi hàn gbangba pé ọpọ àwọn ọlọpaa lo n ri awọn alawọ dúdú bíi oni jagidijagan.

Iru idanilẹkọọ lórí ojuṣaju bayii ti wa láwọn ileeṣẹ nla, ṣugbọn ṣe o n so eso rere?

Ìwádìí kan ti Ọjọgbọn Robin Engel láti fásitì Cincinnati ṣe nílùú New York fi han pe idanilẹkọ náà kò so eso rere.

Ìwádìí miran ti wọn ṣe láwọn ileeṣẹ ọlọpaa lagbegbe New York fi hàn pé ẹkọ naa ko ni ipa kankan lara awọn agbofinro ọhun.

Ọjọgbọn Engel ni "ko si iyatọ kankan ninu bi wọn ṣe n wuwa si."

Ẹ̀rọ ayàwòrán tí wọn n so mọ ara àwọn ọlọpaa

Ẹrọ náà máa n ya aworan ìṣesí awọn ọlọpaa lẹnu iṣẹ, to fi mọ ohun ti wọn n ri ati ohun ti wọn n so ni gbogbo igba lẹnu iṣẹ.

Ọjọgbọn Engel sọ pé àwọn ẹrọ ayàwòrán náà n ṣiṣẹ, ṣugbọn o fi kun pe o ni ipa ninu bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ lára àwọn ọlọ́pàá kan, nigba ti ko ni ipa kankan lára awọn ẹlomiran.

Ẹwẹ, onimọ nípa ètò iṣiro ni fásitì Amherst, to wa ni Massachusetts, Travis Campbell sọ pé, lẹyìn ifẹhonuhan Black Lives Matter to bẹrẹ lọdun 2014, adinku ti dé bá bi awọn ọlọpaa ṣe n pa awọn eeyan dúdú láwọn agbegbe kan.

O ni ìwádìí fi hàn pé adinku dé bá bi awọn ọlọpaa ṣe n pa awọn alawọ dúdú leyin oríṣiríṣi iwọde to n wáyé lórí bí awọn ọlọpaa ṣe n pa awọn alawọ dúdú.

Campbell sọ pe iyatọ gedegbe lo wa laarin awọn agbegbe ti awọn eeyan ti n ṣe iwọde lòdì sí ipaniyan awọn eeyan atawọn ibi ti kò sí iwọde tabi ti iwọde wọn kò lamilaaka to.

Campbell pari iwadii rẹ pé ohun mẹta lo mu ayipada bá bí àwọn ọlọpaa ṣe n ṣiṣẹ sí l'Amẹrika.

Akọkọ ni akitiyan awọn ọlọpaa ọhun lati tu ọmọluabi wọn ṣe.

Ìkejì ni bi awọn eeyan ìlú ko ṣe ni ìgbàgbọ nínú àwọn ọlọpaa mọ.

Ẹkẹta ni bi awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣe gbaruku ti iṣẹ náà.

Lẹyin naa lo sọ pé afojusun awọn awọn ifẹhonuhan to n wáyé káàkiri l'Amẹrika ni bi awọn ọlọpaa yóò ṣe máa ṣiṣẹ wọn bí ọmọluabi, ṣugbọn àṣejù rẹ lè mú kí adinku dé bá ìgbàgbọ àwọn èèyàn ọhun ninu awọn ọlọpaa.